Lẹyin oṣu meji ti wọn ko ọpọ apo irẹsi lọ ni Bodija, awọn aṣọbode tun fọ ṣọọbu awọn onirẹsi l’Ọja Ọba

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lai tii to oṣu meji ti wọn jalẹkun ṣọọbu awọn onirẹsi lọja Bodija, n’Ibadan, ti wọn si ko ọpọlọpọ apo irẹsi lọ, awọn aṣọbode tun ja ṣọọbu awọn oniṣowo l’Ọjaba, n’Ibadan, bakan naa, wọn si tun ko ọpọlọpọ apo irẹsi lọ.

Laarin oru mọju ọjọ kin-in-in-ni, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii, ti i ṣe ọjọ Abamẹta, Satide to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti awọn oniṣowo irẹsi ninu ọja naa ṣadeede ba ilẹkun ṣọọbu wọn ni jija, ti wọn si ri i pe wọn ti ko gbogbo apo irẹsi awọn lọ.

Tẹ o ba gbagbe, loru mọju Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, lawọn aṣọbode ṣe bẹẹ pa awọn oniṣowo irẹsi lẹkun lọja Bodija n’Ibadan.

Iṣẹlẹ akọkọ yii lo mu ki ẹgbẹ awọn oniṣowo ounjẹ tutu ninu ọja naa kọwe ẹsun ta ko ileeṣẹ aṣọbode ilẹ yii nipasẹ Sẹnetọ Kọla Balogun ti i ṣe aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba ilẹ yii niluu Abuja.

ALAROYE gbọ pe bi Sẹnetọ Balogun ṣe jiṣẹ ọhun nileegbimọ tan lawọn aṣofin ti gbe igbimọ kan dide lati ṣewadii ohun to mu ki awọn aṣọbode jalẹkun onilẹkun kọja lọ.

Wọn ko ti i pari iwadii ọhun ti awọn aṣọbode tun fi pa iru itu ti wọn pa ni Bodija fawọn onirẹsi l’Ọja’ba.

Yatọ si ọkẹ aimọye apo irẹsi ati ogunlọgọ kẹẹgi ororo ti wọn ko ninu awọn ṣọọbu naa lẹyin ti wọn fipa ja awọn ilẹkun wọn wọle, ẹgbẹẹgbẹrun owo naira ti awọn oniṣowo naa ko pamọ sinu ṣọọbu wọn la gbọ pe wọn padanu sinu iṣẹlẹ yii.

Ẹnikẹni iba ti mọ pe awọn aṣọbode lo jalẹkun ṣọọbu awọn oniṣowo ni Bodija ti wọn si ko wọn lẹru ọja atowo nla lọ, awọn kọsitọọmu funra wọn ni wọn fi awọn agadagodo mi-in to jẹ tiwọn tun awọn ilẹkun naa ti, ti wọn si tun lẹ iwe mọ ara ilẹkun lati jẹ ki gbogbo aye mọ pe awọn lawọn ṣiṣẹ naa.

Ninu iwe ti wọn lẹ mọ ara awọn ṣọọbu ti wọn ja wọnyi ni wọn ti ṣekilọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ jalẹkun tabi wọ inu awọn ṣọọbu wọnyi lai gba aṣẹ lọwọ awọn, bi eeyan ba dan iru ẹ wo, oluwa ẹ yoo ṣẹwọn ọdun mẹwaa tabi ko fi miliọnu lọna ọgọrun-un naira (N100m) gbara.

Nigba to n b’ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ aṣọbode ẹkun ipinlẹ Ọyọ ati Ọyọ, Ọgbẹni Kayọde Wey fìdí ẹ mulẹ pe ileeṣẹ awọn lo gbe igbesẹ naa loootọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ki i ṣe awa la ṣiṣẹ yẹn, awọn eeyan wa to n mojuto ẹkun Iwọ-Oorun Guusu orileede yii lati olu ileeṣẹ wa niluu Abuja lo ṣe e, mi o si mọ iru iroyin ti wọn gbọ ti wọn fi gbe igbesẹ yẹn.”

Alukoro fun ẹkun kin-in-ni lolu ileeṣẹ aṣọbode ilẹ yii niluu Abuja, Ọgbẹni Theophilus Duniya, naa fidi ẹ mulẹ pe awọn lawọn ṣiṣẹ naa.

O ṣalaye pe “Ijọba ti ṣe e leewọ fawọn oniṣowo lati ma ko irẹsi ilẹ okeere wọ orileede yii nitori iru ọja bẹẹ maa n ko okuta ba awọn nnkan ti a n pese funra wa nilẹ yii ni. Ofin si ti ro wa lagbara lati lọọ maa ko irẹsi ilẹ okeere taa ba ri nibikibi ti wọn ba ko o pamọ si.”

Leave a Reply