Lẹyin ọdun kan Amọtẹkun, awọn gomina ilẹ Ibo naa da ẹṣọ alaabo tiwọn silẹ

Faith Adebọla

Ọrọ aabo to mẹhẹ lorileede yii ati bawọn ọjọgbọn ṣe n pe fun ẹṣọ alaabo ipinlẹ ti dọrọ ailaṣọ lọrun paaka, ti wọn lo to nnkan apewo fawọn ọmọ eriwo, eyi lo mu kawọn gomina ipinlẹ ẹya Ibo naa fori kori, ti wọn ṣi fẹnu ko lati da ẹṣọ alaabo to maa ṣiṣẹ lawọn ipinlẹ wọn silẹ, eyi ti wọn porukọ ẹ ni EBUBEAGU.

Nibi ipade kan to waye nile ijọba ipinlẹ Imo, lọjọ Aiku, Sannde yii, lawọn gomina atawọn eeyan jannkan jannkan lapa ilẹ Ibo ti fontẹ lu ipinnu wọn ọhun lati ṣedasilẹ ẹṣọ alaabo tiwọn, yatọ si awọn ọlọpaa ijọba apapọ.

Awọn gomina to pesẹ sibi ipade naa ni Willie Obiano tipinlẹ Anambra, Okezie Ikpeazu tipinlẹ Abia, Hope Uzodinma tipinlẹ Imo, David Uweze Umahi ti ipinlẹ Ebonyi ati gomina ipinlẹ Enugu, Lawrence Ifeanyi Ugwuanyi.

Yatọ sawọn gomina maraarun yii, ọga ọga patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa to ṣẹṣẹ depo, Usman Alkali Baba, naa wa nipade ọhun, bẹẹ si lawọn olori ẹgbẹ ajijagbara Ohaneze Ndigbo, atawọn aṣoju ileeṣẹ ologun ori omi (Navy) ati tofurufu (Air force) naa peju pesẹ.

Atẹjade kan ti wọn fi lede lori atẹ ayelujara ipinlẹ Imo sọ pe lẹyẹ-o-sọka lawọn maa gbe ofin kalẹ lawọn ileegbimọ aṣofin ipinlẹ maraarun, bi ofin ba si ṣe n delẹ lawọn maa bẹrẹ si i gba awọn ẹṣọ alaabo siṣẹ lati ro eto aabo lagbara.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹsan-an, oṣu ki-in-ni, ọdun to kọja (2020), lawọn gomina ilẹ Yoruba ṣepade, ti wọn si ṣedasilẹ ẹṣọ alaabo fun agbegbe Guusu/Iwọ-Oorun. Amọtẹkun lorukọ ti wọn sọ ikọ alaabo ọhun, lati le ro eto aabo to dẹnu kọlẹ kaakiri agbegbe kan si omi-in lagbara.

Leave a Reply