Gbenga Amos, Abẹokuta
Ṣe ẹ ranti Ọgbẹni Abidemi Rufai, amugbalẹgbẹẹ agba lori iṣẹ akanṣe fun Gomina Dapọ Abiọdun ti wọn yọ nipo lọjọsi, tọwọ ọlọpaa Amẹrika tẹ loṣu Karun-un, ọdun to kọja, fun ẹsun jibiti owo tuulu-tuulu kan to ṣe lori ẹrọ ayelujara, eyi ti wọn tori n ba a ṣẹjọ lọhun-un?
Lẹyin ọdun kan to ti n gbatẹgun lahaamọ wọn, ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) naa ti jẹwọ, o ni loootọ loun huwa jibiti ti wọn fẹsun rẹ kan oun, oun si ti ṣetan lati pọ gbogbo owo toun ko jẹ naa pada patapata, ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ.
Nile-ẹjọ giga kan to wa niluu Tacoma, lorileede Amẹrika, ni afurasi ọdaran naa ti kawọ pọnyin rojọ ara rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un yii, to si jẹwọ pe ko si irọ ninu ẹsun ole jija ati jibiti lilu ti wọn fi kan oun.
Lara ẹsun ti wọn fi kan Abidemi Rufai ni pe o lọọ ṣe ayederu orukọ ati fọto awọn ẹni ẹlẹni kan, o si fi purọ fun awọn alaṣẹ ilẹ Amẹrika lati gba owo iranwọ ti wọn n san fawọn ọmọ ilẹ Amẹrika, latari arun Koronafairọọsi to gbode lọdun 2021 ọhun.
Awọn orukọ ati fọto oriṣiiriṣii to fi sọwọ sọhun-un to ẹgbẹrun lọna ogun, o lawọn eeyan naa nilo iranwọ gidi, tori arun Korona ti n pọn wọn loju, o ni wọn maa nilo to miliọnu meji owo dọla ilẹ Amẹrika, lara owo iranwọ tijọba wọn lọhun-un ṣeto rẹ, ni wọn ba fi ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta owo dọla ($600,000) ṣọwọ si i, lai mọ pe igbo atu lasan ni wọn sanwo si, irọ gbuu ni gbogbo ọrọ ati akọsilẹ ti Abidemi ko jọ.
Eyi to ga ju ninu iwa jibiti ọhun waye nigba to fi ẹtan gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun o le aadọta, ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin ati mẹta owo dọla ($350,763) lọwọ ileeṣẹ ijọba to n ri si ipese iṣẹ lolu-ilu ilẹ Amẹrika to wa ni Washington (Washington State Employment Security Department), wọn lafurasi yii lo ni gbogbo awọn akaunti ti wọn fowo iranwọ naa ṣọwọ si pata.
Bakan naa ni Rufai tun gbowo rẹpẹtẹ lọwọ ẹka to n ran awọn olokoowo keekeekee lọwọ, iyẹn Small Business Administration. Wọn ni laarin ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2020 si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun naa, igba mọkandinlogun ni Rufai kọwe ibeere iranwọ owo fawọn ti Korona ṣakoba fun okoowo wọn, bẹẹ ni wọn si n pese owo naa fun un, ẹgbẹrun mẹwaa owo dọla ($10,000) lo gba lori eyi.
Ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ lọrọ ọkunrin yii gẹgẹ bawọn olufisun rẹ ṣe ṣalaye ni kootu ọhun, wọn ni laarin ọdun 2017 si 2020, leralera ni Rufai gbiyanju lati lu ilẹ Amẹrika ni jibiti owo to fẹrẹ to miliọnu meji dọla ($1.7 million), ofutufẹtẹ ẹsun oriṣiiriṣii to fẹrẹ to ẹẹdẹgbẹrin lo ko kalẹ, to purọ oriṣiiriṣii pẹlu iwe ibeere fun owo. Wọn ni gbogbo ajalu to ba ti ṣẹlẹ l’Amẹrika ni afurasi naa n kọwe ibeere owo le lori, ti yoo sọ pe awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lo n beere owo ọhun.
Nigba ti wọn tẹ pẹpẹ awọn ẹsun naa siwaju Adajọ Benjamin H. Settle tile-ẹjọ giga ọhun, ti adajọ si beere ero rẹ lori awọn ẹsun wọnyi. Olujẹjọ ni wọn ko purọ mọ oun o, ki wọn ṣaa ṣaanu oun ni, ki wọn din iya ẹṣẹ oun ku, o ni gbogbo owo ti kalokalo oun ti gbe mi pata loun maa pọ jade, tori o ti ha oun lọrun bayii.
Amọ afaimọ ni ko ni i jẹ ọgba ẹwọn Amẹrika ni Rufai maa dagba si o, tori agbefọba Amẹrika meji to n ba Rufai ṣẹjọ, Ọgbẹni Seth Wilkinson, ati Ọgbẹni Cindy Chang, ti rọ ile-ẹjọ naa pe ki wọn ma ṣe tun fi idajọ rẹ falẹ mọ, o ni ẹwọn oṣu mọkanlelaaadọrin pere lo wa lakọọlẹ fun awọn kan lara ẹsun naa, ẹwọn ọgbọn ọdun lo si wa lakọọlẹ fun isọri keji ẹsun ti wọn pe ni wire fraud, o ni kadajọ ṣiro gbogbo ẹ mọ ara wọn lo ku.
O ni ko tun si awijare kankan mọ, tori ileeṣẹ ijọba marun-un ọtọọtọ lo ti tuṣu ẹsun wọnyi desalẹ ikoko, ti wọn si fidi okodoro mulẹ, eyi ti afurasi naa ko fi le jiyan rara nipa awọn ẹsun naa. Awọn ileeṣẹ naa ni Department of Labor Office of Inspector General, Internal Revenue Service Criminal Investigations, Department of Homeland Security Office of Inspector General, United States Small Business Administration Office of the Inspector General ati Washington Employment Security Department.
Lẹyin gbogbo atotonu, Adajọ paṣẹ ki wọn da Rufai pada sahaamọ, o ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni oun tun fẹẹ foju kan an, tori ọjọ naa loun yoo gbe idajọ oun kalẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Gomina Dapọ Abiọdun ti yọ ọkunrin naa nipo amugbalẹgbẹẹ agba rẹ ninu oṣu Karun-un, ọdun 2021, ti iṣẹlẹ naa ti waye, o loun o fẹ ko ko eeri igi yi obi iṣakoso oun lara.