Lẹyin ọdun kẹtadinlogoji to ku, awọn eeyan ṣeranti Haruna Ishọla

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe ọdun kẹtadinlogoji ree ti agba olorin Apala nni, Oloogbe Alaaji Haruna Ishọla Bello, ti jade laye, sibẹ, orukọ baba naa ko parẹ, bẹẹ lawọn orin to ṣe silẹ ṣi wa lọja, ti wọn n ta titi doni.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla yii, lo pe ọdun mẹtadinlogoji (37) ti Haruna Ishọla jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta (64).

Iku ọhun ka awọn onifaaji igba naa lara pupọ, bẹẹ ni kaluku n sọ pe ta ni yoo ṣe bii Haruna Ishọla, baba to jẹ ori ijokoo ni i ti kọrin rẹ, to si jẹ pe ọrọ kan, owe kan, ni yoo fi maa da awọn eeyan laraya pẹlu awọn ede ati aṣa to nitumọ gidi.

Lasiko ti Haruna Ishọla ti wọn n pe ni Baba -n- Gani agba n lo saa, ko si elere naa ti ko ni i bọwọ fun baba ti wọn bi niluu Ijẹbu-Igbo lọdun 1919 ọhun. Oloogbe Ayinla Ọmọwura tilẹ fi kọrin nigba kan pe ‘ninu gbogbo elere agbaye pata, Ishọla mo fia (fear)ẹ ju. Olorin ti yoo sọ pe ti Baba Musiliu bawo ko si jare.’

Nigba ti Ọlọrun yoo si ṣe e, iṣẹ Haruna ko parẹ gẹgẹ bii orukọ rẹ naa ni, nitori ọmọ rẹ, Musiliu Haruna Ishọla, tẹwọ gba ere Apala, o si n ri i ṣe latọdun 1983 ti baba rẹ ti jade laye, bẹẹ lo n kọrin naa lọ titi doni.

Leave a Reply