Lẹyin ọdun marun-un to ti wa nipo, ile-ẹjọ yẹ aga mọ ọba nidii ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo, ti yọ Alhaji Adewale Lawal nipo gẹgẹ bii, Ọba Olu-Ararọmi Ọpin, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, lẹyin ọdun marun-un ti ọrọ ọba ọhun ti wa ni ile-ẹjọ.

Onidaajọ Muhamad AbdulGafar lo gbe idajọ naa kalẹ nile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, o ni Alhaji Lawal ko lẹtọọ lati fi ara rẹ jọba ni ilu Ararọmi, to wa ni abẹ ọba miiran, fun idi eyi, ko gbọdọ pe ara rẹ ni ọba mọ lati wakati naa lọ. Nigba to n tẹsiwaju ninu idajọ rẹ, o ni agboole ni Ararọmi jẹ si ilu Isọlọ Ọpin, ti ko si ṣee ṣe ki wọn ni ọba meji lẹẹkan ṣoṣo tori pe awakọ meji ko le wa ọkọ ẹyọ kan.

ALAROYE gbọ pe lati bii ọdun marun-un sẹyin, ni ẹjọ ti wa nile-ẹjọ lori oye ọba jijẹ laarin ilu Ararọmi ati Isọlọ Ọpin. Ilu Ararọmi yan ọba, sugbọn ilu Isọlọ ni wọn o ni ẹtọ lati jọba tori pe abẹ Isọlọ ni wọn ṣi wa. Ile-ẹjọ ti waa fidi ẹ mulẹ pe ilu Ararọmi ko le da ọba jẹ loootọ, tori abẹ Isọlọ ni wọn wa.

Idajọ yii mu ki ayọ awọn araalu Isọlọ kun, nigba ti Ọba Asọlọ ti ilu Isọlọ, Ọba Raphael Sunday Are, n sọrọ lorukọ gbogbo araalu, o ni inu awọn dun si bi ile-ẹjọ ṣe fidi ẹ mulẹ pe, Ararọmi o le da ọba ti wọn ni, eyi tumọ si pe ilu mejeeji ko le yara wọn sọtọ, tori pe, abẹ ilu Isọlọ ni wọn wa, ati pe eyi yoo tun mu ibaṣepọ ati iṣọkan to dan mọran wa laarin ilu mejeeji.

Kabiyesi tẹsiwaju pe, ki oun too jọba, ilu Ararọmi ni oun n gbe, kọda ọba to jẹ ṣaaju oun, Ọba Michael Dada Oyedele, ilu Ararọmi lo n gbe ki wọn too fi i jọba niluu Isọlọ, to si kọle si Ararọmi pẹlu, eyi fihan pe ọkan ṣoṣo ni ilu mejeeji, wọn o si le ni ọba meji.

Ninu ọrọ ti Lawal, o ni oun yoo wa asiko lati ṣe agbeyẹwo ẹjọ ti ile-ẹjọ da daadaa, ki oun le mọ igbeṣẹ to kan lati gbe. O ni lotitọ idajọ yii segbe lẹyin ilu Isọlọ Ọpin, sugbọn Ararọmi Ọpin ni ilu awọn yoo maa jẹ titi laelae tori pe ilu awọn ti wa tipẹ.

Leave a Reply