Lẹyin ọdun marundinlaaadọta to ti wa nile ọkọ, iya aadọrin ọdun bimọ fun igba akọkọ laye rẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko sigba ta a daṣọ ti a ko rilẹ fi wọ lọrọ iya agbalagba ẹni aadọrin ọdun (70) torukọ ẹ n jẹ Jivunben Rabari, iya naa pẹlu ọkọ ẹ, Maldahari, ẹni ọdun marundinlọgọrin(75) ṣẹṣẹ bi akọbi wọn bayii ni.

Tayọ-tayọ ni wọn fi ki ọmọkunrin jojolo naa kaabọ, wọn n dupẹ pe awọn ri ọmọ awọn bo ti wu ko pẹ to.

Ọmọ orilẹ-ede India lawọn tọkọ-taya yii, wọn ti ṣegbeyawo ọna ti jin. Gbogbo iyanju ti wọn gba lati lọmọ laye ko bọ si i rara, ṣugbọn wọn ko duro, wọn ṣaa n wa ọna ti ọlẹ ayọ yoo fi sọ ninu iya naa bo ti darugbo to ni.

Ilana ti wọn fi n bimọ igbalode ti wọn n pe ni IVF ni wọn tun lọọ ba awọn dokita fun, pe ki wọn jẹ kawọn naa ṣe e wo, boya Ọlọrun yoo gba aajo.

Dokita Naresh Bhanushali ti wọn lọọ ba sọ fun wọn pe wọn ti dagba kọja eto ọmọ bibi igbalode naa, ki wọn kuku gba f’Ọlọrun lori airomọbi wọn.

Ṣugbọn awọn tọkọ-taya naa ko gba, wọn sọ fun dokita pe eto to ni kawọn ma ṣe yii ni awọn kan ṣe ninu ẹbi awọn ti wọn fi di ọlọmọ, wọn ni to ba le jẹ fawọn famili awọn ọhun, yoo jẹ fawọn naa ni wọn ba ṣe e.

Nigba ti Ọlọrun yoo si gbe aanu rẹ de, kinni naa jẹ fawọn tọkọ-taya ti wọn n gbe labule Mora, ni Gujurat, India naa. Iya agba loyun lẹyin ọdun marundinlaaadọta (45) to ti wọle ọkọ. Nigba to si to asiko kọmọ waye, awọn dokita ṣe ohun to yẹ fun iya agba yii, ni wọn ba gbe ọmọ rẹ le e lọwọ.

Awọn dokita yii paapaa ko yee sọ pe nnkan ijọloju lo jẹ fawọn pe awọn arugbo yii ri IVF ṣe, wọn ni awọn ti wọn ṣi wa ni ṣango ode ki i ri i mu nigba mi-in, bo ṣe bọ si i fawọn agbalagba yii kọja oye awọn.

Ṣugbọn iya agba ti bimọ na, ọkọ rẹ naa kun fun ayọ pataki, nigba tọwọ wọn tẹ ohun ti wọn ti n fọjọ aye wọn gbogbo wa.

Leave a Reply