Adewale Adeoye
Gbajumọ oṣere tiata nni, Shaffy Bello, ti sọ idi pataki to ṣe jawee ikọsilẹ fun ọkọ rẹ, Ọgbẹni Akinrimisi, tawọn mejeeji ti jọ n ṣe lọkọ-laya lati nnkan bii ọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin.
Shaffy ni ilu oyinbo to n gbe latigba tawọn ti fẹra awọn jin ju foun lati maa paara nigba gbogbo gẹgẹ b’oun ti ṣe maa n ṣe tẹle, oun ko si le fara da a mọ rara loun ṣe gbe igbesẹ naa.
O sọro yii di mimọ lori eto kan ti wọn pe e si. Oṣere yii ni nigba toun kọkọ fẹ ọko oun yii, oun ko r’ohun to buru nibẹ rara lati maa lọ siluu Amẹrika, nibi to fi ṣebugbe nibẹrẹ aye rẹ rara, ṣugbọn nigba ti ọjọ n gori ọjọ, ti Ọgbẹni Akinrimisi ko si ṣetan lati pada wa sorileede yii lati maa waa gbe pẹlu oun loun ṣe kuku pa ọkan oun pọ, toun si gba lati kọ ọ silẹ, koun le maa ba igbesi aye oun lọ.
Shaffy ni, ‘Ọkọ daadaa ni Akinrimisi ti i ṣe baale mi tẹlẹ, oun ni mo si bi awọn ọmọ mejeeji ti mo bi fun.