Lẹyin ọdun mẹẹẹdogun, ọba tuntun jẹ niluu Fiditi

Faith Adebọla

Orin ati ijo lo gba ilu Fiditi, nijọba ibilẹ Afijio kan, nipinlẹ Ọyọ, lọjọ Aje, Mọnde yii, ọjọ naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, gbe ọpa aṣẹ ati irukẹrẹ le ọba Oyewọle Sikiru Oyelere lọwọ lati sami si ibẹrẹ iṣakoso rẹ gẹgẹ bii Onifiditi ti ilu Fiditi tuntun.

Eto naa waye nileejọba ijọba ibilẹ Afijio, niluu Jobele, ipinlẹ Ọyọ.

Ṣaaju, iyẹn lati ọjọ kejilelogun, oṣu kẹta, ọdun 2018, ni ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ gomina tẹlẹ, Sẹnetọ Isiaka Ajimọbi, ti buwọ lu iyansipo ọba tuntun yii, ṣugbọn eto gbigba ọpa aṣẹ rẹ ko le waye titi ti iṣakoso naa fi kogba sile lọdun 2019.

Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 1967, ni wọn bi Ọba Oyewọle Oyelere si idile Ọmọọba Adekunle Oyelere ti i ṣe baba rẹ, ni ila idile ọlọba Asu, Sidikat Abẹkẹ Oyelere ni iya rẹ.

Kabiyesi lọ sileewe pamari Baptist Nursery School, niluu Fiditi, ati AUD Primary School, niluu ọhun, ko too kọja si Saint Anthony Primary School, to wa niluu Awẹ lati pari ẹkọ rẹ.

O lọ sileewe girama St. Joseph, latigba naa lo si ti n ṣiṣẹ nileeṣe mọnamọna ilẹ wa, NEPA. Ẹnu iṣẹ naa lo wa to fi lọọ kawe ni Ọṣun State College of Technology, ni Ẹsa Oke, nipinlẹ Ọṣun, o si gboye jade ninu imo iṣiro owo (Accountancy).

Ko kuro nileeṣẹ NEPA ọhun to fi di ti aladaani, Power Holding Company of Nigeria, PHCN, ati Ibadan Electrical Distribution Company (IBEDC), lẹyin naa lo fẹyinti loṣu keje ọdun yii.

Ọpọ ọdun ni ọkunrin naa ti fi ṣatilẹyin fun idagbasoke ilu Fiditi, o wa ninu oriṣiiriṣii ẹgbẹ idagbasoke ilu, ki ori too ṣe e loore, ti wọn yan an sipo ọba yii.

Ireti awọn araalu ati adura wọn ni pe igba Ọba Oyelere yii yoo san ilu Fiditi, yoo si tuba-tuṣẹ.

Leave a Reply