Lẹyin ọdun mẹẹẹdogun: Ọbasanjọ ati Gani Adams pari ija, nitori iṣọkan ilẹ Yoruba

Aderounmu Kazeem

Lẹyin ọdun mẹẹdogun, ija to wa laarin Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Aarẹ Gani Adams ti pari patapata.

Lẹkki, l’Ekoo, nile ọkan lara awọn agbaagba inu ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ, ni wọn ti ba wọn yanju aawọ naa, eyi to ti wa laarin wọn lati nnkan bii ọdun mẹẹdogun sẹyin nigba ti Ọbasanjo fi wa nipo Aarẹ Naijiria.    

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, koko ipade ọhun ni lati wa bi awọn agbaagba Yoruba mejeeji yii yoo ṣe pari aawọ to ti wa laarin wọn fun ọdun pipẹ, ti iṣọkan, ati ijiroro yoo si maa waye pẹlu awọn agbaagba Yoruba mi-in lati ṣeto ọjọ ọla to dara fun iran ọmọ alade.

Ninu ọrọ Iba Gani Adams lo ti sọ pe ipade alaafia ọhun ko ṣai da lori bi irẹpọ yoo ṣe wa laarin awọn agbaagba ilẹ Yoruba, ati bi eto aabo yoo ṣe fẹsẹ rinlẹ daadaa nilẹ Yoruba atawọn nnkan mi-in to le mu ilọsiwaju waye.

Lọdun 2005, lasiko ti Ọbasanjọ, wa lori ipo aleefa, lo paṣẹ ki awọn ẹṣọ agbofinro mu Gani Adams ati Oloogbe Frederick Fasehun, lori wahala tawọn ọmọ ẹgbẹ OPC da silẹ lagbegbe Agege, l’Ekoo, ninu eyi ti ọpọ dukia ti ṣofo danu.

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, to wa nibi ipade ọhun ni Yinka Odumakin; Baṣọrun Ṣẹgun Sanni; Ọgbẹni Akin Ọṣuntokun atawọn mi-in ti wọn jẹ eekan ninu ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba yii.

Leave a Reply