Gbenga Amos, Abeokuta
Ologere ti Ogere Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, Ọba Ọladele Ogunbade, ti darapọ mọ awọn baba nla rẹ.
Ba a ṣe gbọ, Ọba alaye yii waja loru mọju ọjọ Aje, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lẹyin aisan ranpẹ. Ẹni ọdun marundinlaaadọrun-un ni Kabiyesi naa.
Nigba to n tufọ ipapoda ọba yii lọjọ Tusidee, Olootu Ọmọọba ilu Ogere Rẹmọ, Dokita Owodunni Adekunbi, ṣapejuwe iku ọba naa bii adanu nla fun ilu Ogere, ati ilẹ Rẹmọ lapapọ.
O lo maa ṣe diẹ ki Ogere too ri iru ẹni to maa da bii ọba to waja yii, tori baba daadaa ni.
Wọn ni ijiroro ṣi n lọ lori eto isinku rẹ, wọn yoo si kede rẹ laipẹ.