Lẹyin ọdun mejila ti ko ti sina, ijọba fẹẹ da ina ẹlẹntiriiki pada si ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Gbogbo eto lo ti pari lọdọ ijọba lati da ina ẹlẹntiriiki pada si awọn ilu to wa lẹkun Guusu ipinlẹ Ondo lẹyin bii ọdun mejila sẹyin ti wọn ti wa ninu okunkun biribiri.

Alaga igbimọ to n mojuto ọrọ atunṣe ina ọba lẹkun Guusu, Ọba Festus Olumoyegun (Oniju ti Iju-Odo), lo sọrọ yii lasiko to n jabọ abajade ipade wọn fun Gomina  Rotimi Akeredolu lọfiisi rẹ to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Ọba Olumoyegun fi da gomina loju pe gbogbo igbiyanju ijọba la ti bii ọdun meji aabọ sẹyin lori bi ina yoo ṣe tan pada ko ni i pẹẹ so eso rere.

O ni adehun ti wa laarin igbimọ ọhun ati aṣoju ileesẹ BEDC (Benin Electricity Distribution Company) pe ibi ti  ina ẹlẹntiriiki to wa ni Ọmọtọṣọ, nijọba ibilẹ Odigbo, ni wọn yoo ti fun awọn ilu to wa lẹkun Guusu ni ina.

O ni tayọtayọ loun fi n sọ fun awọn ilu tọrọ kan ki wọn maa reti ina ijọba titi ipari oṣu kọkanla, ọdun ta a wa yii.

Leave a Reply