Adewale Adeoye
Beeyan ba gẹṣin nikun awọn gende mẹfa kan ti adajọ ile-ẹjọ MaJisireeti kan niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, tu silẹ laipẹ yii, tọhun ko ni i kọ ẹsẹ rara, ṣinkin ni Inu gbogbo wọn n dun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjo kejilelogun, oṣu Kẹjọ yii, lẹyin ti adajọ ile-ẹjọ naa, Onidaajọ Bọla Ọṣunsanmi, tu wọn silẹ pe ki wọn maa lọ sile layọ ati alaafia. Ẹsun tijọba Eko fi kan wọn ni pe wọn kopa buruku lasiko iwọde ifẹhonuhan EndSARS tawọn araalu ṣe jake-jado orileede yii niluu Eko, nibi ti wọn ti ba ọpọ dukia olowo iyebiye to jẹ tijọba ati tawọn araalu jẹ. Awọn mẹfa naa ni Daniel Joyibo, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Adigun Sodiq, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Kẹhinde Shola, ẹni ọdun mejilelọgbọn, Aalaideen Kamilu, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Sodiq Usseni, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Azeez Isiaka, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn.
Gbogbo wọn pata ni wọn sọ niwaju Onidaajọ Bọla Ọṣunsanmi, pe awọn jẹbi ipa buruku tawọn ko laarin ilu Eko lasiko iwọde ifẹhonuhan ọhun. Wọn rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ ọhun pe ko ṣiju aanu wo awọn, nitori pe awọn ko mọ nnkan tawọn n ṣe lasiko tawọn dawọ le e.
Adajọ ni wọn jẹbi gbogbo ẹsun tawọn agbofinro ipinlẹ Eko fi kan wọn, o si ni ẹwọn ni idajọ to yẹ ki wọn gba gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe ofin ipinlẹ Eko.
Ṣa o, o pada tu gbogbo wọn silẹ nitori to sọ pe wọn ti lo kọja iye ọdun to yẹ ki wọn lo lọgba ẹwọn Kirikiri ti wọn wa lati ọjọ yii wa.
O gba wọn lamọran pe ki wọn ma ṣe dalu ru mọ, ati pe ki wọn di atunbi lẹyin ti wọn jade kuro lahaamọ ti wọn wa fọdun mẹrin sẹyin bayii.