Lẹyin ọdun mẹsan-an, Oyetọla gbọpa aṣẹ fun Ọwaloko Ijẹṣa tuntun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti parọwa si Ọwaloko ti Iloko-Ijeṣa tuntun, Ọba Akeem Ogungbangbe, Ajagbusi-Ẹkun Kẹfa, lati dari awọn eeyan ilu rẹ pẹlu ifẹ, ki alaafia ti gbogbo eeyan mọ ilu naa mọ le maa tẹ siwaju.

Nibi ayẹyẹ dide ade ati gbigbe ọpa-aṣẹ fun Ọba Ogungbangbe, eyi to waye niluu naa lọjọ Abamẹta, Satide, ni gomina ti sọ pe bi wọn ṣe jẹ ọba ọhun lai si wahala fi han pe ilu to fẹran alaafia ni Iloko-Ijeṣa jẹ.

Oyetọla ṣalaye pe opo pataki tiṣejọba oun duro le lori ni alaafia ati ipese awọn nnkan amayedẹrun fun awọn araalu, eyi naa lo si yẹ ki gbogbo eeyan maa lepa rẹ.

O rọ Ọwaloko lati fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo awọn lọbalọba to ku nipinlẹ Ọṣun ati kaakiri orileede Naijiria, bẹẹ lo ke si awọn ori-ade lati maa polongo iṣẹ rere tijọba ba n ṣe nilu ẹnikọọkan wọn.

Ninu ọrọ Ọwa Obokun, Ọba (Dokita) Adekunle Aromọlaran, o ba Ọwaloko tuntun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aanu to ri gba lati bọ sori itẹ awọn baba nla rẹ, o si ke si awọn ọmọ ilu naa lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ.

Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Keji, ṣadura ẹmi gigun ati alaafia fun Ọwaloko, o rọ ọ lati jẹ ọba to n dari pẹlu ibẹru Ọlọrun, bẹẹ lo pe fun ifọwọsowọpọ awọn araalu fun un.

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Ọba Ogungbangbe sọ pe oun mọ pe ọwọ Ọlọrun wa ninu bi oun ṣe de ipo naa. O ni gbagada ni ilẹkun aafin oun ṣi silẹ fun awọn ọmọ ilu oun.

Kabiesi fi kun ọrọ rẹ pe oun yoo ri i pe ibagbepọ alaafia to wa laarin Iloko-Ijeṣa atawọn ilu to yi i ka tẹsiwaju, bẹẹ ni oun yoo si tẹ siwaju ninu ipilẹ rere ti Ọwaloko ana, Ọba Ọladele Ọlashore, ti fi lelẹ.

Lara awọn ti wọn wa nibi eto naa ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun ati igbakeji rẹ, Oloye Adebisi Akande ati Ọtunba Iyiọla Omiṣore, Ọjọgbọn Olu Aina, Akọwe funjọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn ọba alaye kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ninu eyi ti a ti ri Oluwo tilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, Ọwa ti Ẹsa-Oke ni wọn wa nibẹ.

Ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 1964, ni wọn bi Ọba Ogungbangbe sinu idile Alhaji Benjamin Oyediji Taiwo Ogungbangbe ati Ọmọọbabinrin Victoria Ogungbangbe, baba rẹ si ni Imaamu Agba ilu Iloko-Ijeṣa nigba aye rẹ.

O ṣegbeyawo pẹlu Olori Modupẹọla Kikẹlọmọ Ogungbangbe to jẹ ọmọ Ita-Ọffa, niluu Ileṣa, Ọlọrun si fi awọn ọmọ rere kẹ igbeyawo naa.

Leave a Reply