Jide Alabi
Iroyin kan ti wa nita bayii nipa Ṣeun Kareem, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Ẹgbẹgbẹ, wọn lo ṣee ṣe ki igbẹjọ lori ọrọ ẹ tun waye lọjọ kẹfa oṣu kẹwaa ọdun yii, lẹyin to ti lo ọdun mẹta gbako lọgba ẹwọn nibi ti wọn gbagbe ẹ si.
Gbajumọ nla ni ọdọmọkunrin yii, lara ohun tawọn eeyan mọ ọn si daadaa ki wahala ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an yii too ṣẹlẹ ni ṣiṣe igbelarugẹ fawọn olorin, to si tun maa n gbe sinima Yoruba jade. Oun paapaa ti sọ ọ ri wi pe, oun lawọn mọto akero to maa n pawo wale foun daadaa, bẹẹ loun tun ni ile itura tawọn eeyan ti maa n gbafẹ.
Ohun tawọn eeyan mọ mọ Ṣeun Egbẹgbẹ ree o, ki ariwo too gbalu wi pe, ọkunrin naa ni awọn ohun mi-in to n ṣe daadaa ni ikọkọ.
Ile-ẹjọ giga (Federal High Court) l’Ekoo lọkunrin yii ti kọkọ foju han niwaju Adajọ Olurẹmi Oguntoyinbo ninu oṣu keji ọdun 2017. Latigba naa lo ti wa lọgba ẹwọn.
Ṣeun Ẹgbẹgbẹ atawọn eeyan wọnyi, Oyekan Ayọmide, Lawal Kareem, Ọlalekan Yusuf ati Muyideen Shoyọmbo ni wọn jọ fi ẹsun jibiti ati idigunjale kan. Ẹsun bii ogoji ni wọn si ka si wọn lẹsẹ.
Lara ẹsun ti wọn fi kan Ẹgbẹgbẹ atawọn oluku ẹ ni pe wọn lu awọn Hausa ti wọn maa n ṣẹ owo dọla ni jibiti owo to fẹẹ to ogoji miliọnu naira (N39, 098,100), ẹgbẹrun lọna aadọrun owo dọla ($90,000) ati owo to fẹẹ to ẹgbẹrun mẹtala owo Euro (£12,550)
Wọn ni bo ṣe gba owo yii kaakiri lọwọ awọn Hausa to n ṣẹ owo ilẹ okeere si owo ilẹ wa niyẹn o, ati pe aẁọn Mọla onidọla ọhun to fara gba a, wọn a fẹẹ to bii ọgbọn kaakiri ipinlẹ Eko laarin ọdun 2015 si 2017.
Ohun ti a n gbọ bayii ni pe o ṣee ṣe ki igbẹjọ waye lori ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin yii lẹyin ọdun mẹta o le to ti wa lọgba ẹwọn. Ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa ọdun yii ni wọn sọ pe Ẹgbẹgbẹ yoo tun wa si kootu lẹẹkan si i, lẹyin ọpọlọpọ oṣu to ti wa ni ahamọ ijọba.
Ṣe ni nnkan bi ọdun mẹta sẹyin ni wahala ọhun bẹrẹ wẹrẹ ladugbo kan n’Ikeja l’Ekoo nibi ti wọn ti n ta ọpọlọpọ foonu alagbeeka, kọmputa atawọn ẹrọ igbalode mi-in tawọn eeyan n lo. Awọn ọmọ Ibo lo fẹẹ pọju nibi ti a n sọ yii, nibẹ gan-an ni wọn sọ pe Ṣeun Ẹgbẹgbẹ lọ, ko si ohun meji to lọ ṣe nibẹ, wọn ni foonu Iphone olowo nla nla ni ọkunrin yii lọ ji gbe pẹlu awọn eeyan kan ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi.
Nibẹ gan an lọwọ ti tẹ ẹ, Iphone mẹwaa ni wọn ba lọwọ ẹ pẹlu, tọrọ ọhun si di ti ọlọpaa. Alaye ti Ṣeun Ẹgbẹgbẹ ṣe ni kete to bọ lọwọ awọn ọlọpaa ni pe, oun ko jale o, wọn kan fẹẹ fi iṣẹlẹ ọhun ba oun lorukọ jẹ ni.
Ọrọ ọhun fẹẹ ma ti i lọ silẹ, ṣadeede lariwo tun gba ilu laarin ọsẹ meloo kan sira wọn wi pe wọn tun ti mu Ṣeun lagbegbe kan l’Ekoo, ati pe owo dọla ati Euro to fẹẹ ji gbe lọwọ awọn Hausa ti wọn maa n ṣe pasipaarọ owo lo koba a.
Nibẹ yẹn gan-an ni wahala buruku ti de ba oun atawọn ẹmẹwaa, n lọrọ ọhun ba dele-ẹjọ ti igbẹjọ si bẹrẹ lojuẹsẹ.
Gbogbo akitiyan agbẹjọro ẹ lati wa beeli fun ọkunrin yii lo jasi pabo o, nitori niṣe ni adajọ ni ko lọ wa owo iduro miliọnu marun-un naira wa, bẹẹ lo tun gbọdọ ni oniduro meji ti wọn yoo je ọga patapata lẹnu iṣẹ ijọba. Nibẹ yẹn gan-an ni idaamu buruku yii ti de ba Ṣeun Kareem.
Wọn lohun to ṣẹlẹ ni pe, ọkunrin naa ko ri eeyan kan bayii duro fun un nitori ko sẹni to fẹẹ fi iṣẹ ẹ tabi orukọ rere ẹ ṣere. Bi ko ṣe ri oniduro ati owo miliọnu marun-un naira ti won sọ niyen, ti ọrọ ẹ si dabi ẹni ti wọn sọ pe yoo pẹ lẹwọn ju ọbọ lọ.
Ni kete ti wahala ọhun ṣẹlẹ, pupọ ninu awọn eeyan ẹ lo sa fun un, koda lagbo awọn oṣere to ti lẹnu daadaa, yẹyẹ ni wọn n fi ọrọ ẹ ṣe, ti ko si si onifuji kan bayii, to tun kọrin ki i mọ.
Ọkunrin olorin hip-hop kan tiẹ gbe orin kan jade to pe ni Jẹ ki n fun wọn l’Ẹgbẹgbẹ, eyi to fi ṣalaye bi gbogbo ọrọ ọhun ṣe jẹ pata.
Ni bayii, adura tawọn eeyan ẹ n gba bayii ni pe ki Ọlọrun ṣiju aanu wo o, ki ọrọ ẹ yanju lọjọ kẹfa oṣu kẹwaa to n bọ yii nigba ti igbẹjọ yoo tun waye ni kootu.
Ki olorun ko sanu fun