Lẹyin ọdun mẹwaa to ti n w’ọmọ lobinrin yii bi ibeji, ọjọ kẹta lo dagbere faye

Inu ọfọ ati ibanujẹ nla ni awọn eeyan obinrin yii, Abilekọ Gloria Chiaka Aderibigbe, ṣi wa bayii, pẹlu bi obinrin naa ṣe dagbere faye lọjọ ọdun Keresimesi to kọja, lẹyin to bi ibeji tan.

Ẹnikan to sọ iṣẹlẹ iku Iyaabeji yii di mimọ loju opo Fesibuuku, Nancy Chika, to jẹ aburo obinrin naa, ṣalaye pe ọdun kẹwaa ree ti Abilekọ Aderibigbe ti ṣe igbeyawo to si ti n woju Oluwa fun ọmọ rere.

O ni adura naa ko tete gba, afi lọdun 2021 to kọja yii ti Ọlọrun da a lohun, to loyun, to si fi oyun ọhun bi ibeji lanti-lanti.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun 2021, ni Gloria bi awọn ibeji naa, ti tẹbi-tara si n ba a dupẹ, ti wọn n ki i ku oriire lẹyin ọdun rẹpẹtẹ to ti n fomije beere ọmọ lọwọ Oluwa.

Ṣugbọn bo ṣe bi awọn ọmọ naa tan lọjọ Alamisi ọhun ni awọn wahala kan to rọ mọ ibimọ bẹrẹ si i ṣẹlẹ, to si di pe wọn waa fi mọto ti wọn fi n gbe alaisan (ambulance) gbe obinrin naa lọ sibi ti wọn yoo ti tọju rẹ si i.

Aburo rẹ yii tilẹ sọ pe oun ri i bo ṣe n gbiyanju ninu ọkọ naa lati ja ajaye, ti ara n ni ẹgbọn oun, ṣugbọn to n tiraka lati duro ṣe iya awọn ọmọ rẹ. O loun di ọwọ rẹ mu, oun ko mọ pe arimọ toun yoo ri i niyẹn.

Afi bo ṣe di ọjọ kẹta lẹyin ti Gloria bimọ tan, iyẹn lọjọ ọdun Keresimesi, ti Iyaabeji tuntun naa dagbere faye, to si fi awọn ọmọ to ti n tọrọ tipẹ naa silẹ lojiji, to darapọ mawọn ara ọrun.

Latigba ti iṣẹlẹ aburu naa ti ṣẹlẹ ni nnkan ko ti ri bo ṣe yẹ ko ri mọ nile oloogbe yii, adura tawọn eeyan si n ṣe fun idile rẹ ni pe k’Ọlọrun fun wọn lagbara ti wọn yoo fi gbe iṣẹlẹ buruku naa kuro lọkan, ko si da awọn ẹjẹ ọrun ti iya wọn ko duro wo wọn yii si.

Leave a Reply