Lẹyin ọdun mọkanla ti ọba wọn ti waja, wọn yan Onirun t’Irun Akoko tuntun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe ni idunnu ṣubu layọ fawọn eeyan ilu Irun Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, lẹyin tawọn afọbajẹ ilu ọhun dibo yan Onirun ti Irun tuntun, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lẹyin ọdun mọkanla ti ọba wọn ti waja.

Mẹjọ lawọn afọbajẹ to n dibo yan ọmọ oye niluu Irun, ṣugbọn awọn marun-un pere lo raaye wa sinu ọgba sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, eyi to wa niluu Oke Agbe, lọsan-an ọjọ naa.

Ọkan ninu awọn afọbajẹ ọhun la gbọ pe o ti ku, nigba ti a ko rẹni sọ fun wa idi tawọn meji fi kọ lati yọju sibi ti wọn ti fẹẹ dibo yan ọba mi-in.

Awọn mararun-un ni wọn dibo fun Ọmọọba Samuel Bayọde Agboọla nigba ti alatako rẹ, Ọmọọba Amos Adebayọ, ko ni ibo kankan.

Ọdun kọkanla ree ti Onirun to jẹ kẹyin, Ọba Williams Adeusi ti waja, lojiji ni ọmọ rẹ kan ti wọn fi jẹ adele lẹyin iku baba rẹ naa tun fo sanlẹ to ku laipẹ rara lori oye, ọkan-o-jọkan awuyewuye to n suyọ laarin awọn idile to n jọba wa lara idi ti ipo ọba ilu ọhun fi ṣofo lati igba naa.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, lawọn agbaagba ilu atawọn ọdọ kan lọọ fẹhonu han ninu ọgba sẹkiteriati to wa l’Oke Agbe lori bi alaga ijọba ibilẹ naa, Alagba Ayọdele Akande ati olori ẹka to n ṣakoso nijọba ibilẹ ọhun, Ọgbẹni Ade Ajibogun, ṣe kọ lati buwọ lu yiyan Onirun tuntun lẹyin ti ijọba ipinlẹ Ondo ti fun wọn lasẹ lati ṣe bẹẹ.

Awọn olufẹhonu han ọhun sọ lọjọ naa pe nnkan ko ni i rọgbọ mọ ti awọn alasẹ ijọba ibilẹ naa ba fi kuna lati fọwọ siwee to yẹ, o pẹ tan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.

Awọn ilu mi-in l’Akoko ti wọn ṣi wa lai ni ọba lati bii ọdun gbọọrọni: Ifira, Ugbe, Ibọrọpa, Ikakumọ, Akunnu, Iye, Igasi, Efifa, Ajọwa ati Ọra Akoko.

 

 

Leave a Reply