Lẹyin ọjọ karun-un to bẹrẹ isẹ, ọmọọdọ dumbu ọga rẹ bii ẹran l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Titi di ba a ṣe n sọrọ yii ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣì n wa ọmọọdọ kan to dumbu ọga rẹ, Abilekọ Adedayọ Caroline Feyiṣara ẹni tawọn eeyan tun mọ si Iya Kẹmi olounjẹ bi ẹran ileya niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo.

Ọkan ninu awọn ọmọ oloogbe, Kẹmisọla Ayanṣọla, ṣàlàyé fun akọroyinwa pe iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii aago marun-un idaji lagbegbe ori oke kan ti wọn n pe ni Ifọkanbalẹ, eyi to wa loju ọna Sabo.

Abilekọ yii jẹ ko ye wa pe isẹ ounjẹ tita ni mama naa n ṣe nigba to wa laye, bẹẹ ni ọjọ ti pẹ diẹ to ti wa lẹnu isẹ naa. Agbegbe Lipakala, loju ọna marosẹ Ondo siluu Ọrẹ lo wa to ti n ta ounjẹ fawọn onibaara rẹ.

Ọmọ Kalaba kan lo kọkọ gba to n ba a ṣiṣẹ, odidi ọdun mẹrin ni onitọhun si fi wa lọdọ rẹ bii ọmọ ọdọ lai si wahala tabi ede aiyede kankan laarin wọn.

Ipari ọdun to kọja ni ọkunrin naa sọ fun ọga rẹ pe oun ko ni i le tẹsiwaju lati maa ba a ṣiṣẹ mọ nitori pe oun ti pinnu lati bẹrẹ si i kọṣẹ ọwọ lati ibẹrẹ ọdun ta a wa yii lọ.

Oun naa lo si ṣeto bí afurasi apaayan yii ṣe de ọdọ obinrin ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

Alẹ ọjọ Aiku ni oloogbe ọhun si pe ọmọ rẹ, Kẹmisọla, sori aago, to ni ko tete kọ awọn ẹbẹ adura to ba ni ransẹ soun nitori pe aarọ ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aje lawọn fẹẹ bẹrẹ aawẹ biribiri, eyi ti wọn fi maa n pari aawẹ ogoji ọjọ ti awọn Kristiẹni n gba wọnu ọdun Ajinnde ni sọọsi awọn.

Kẹmi ni oun pe iya awọn sori aago rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ṣugbọn ipe naa ko wọlé, oun tun gbiyanju lati pe ẹnikan to wa nitosi ṣọọbu rẹ lati beere lọwọ onitọhun boya obinrin naa wa ni ṣọọbu to ti n ta ounjẹ, ṣugbọn ti ẹni to pe jẹ ko ye e pe titi gbọin gbọin ni ṣọọbu ọhun wa.

Alaga adugbo ti iya wọn n gbe to pada pe lo sọ fun un pe ko tete maa bọ nile lai sọ ohun to sẹlẹ fun un ní pato.

Nigba ti oun ati ẹgbọn rẹ obinrin kan yoo si fi de bẹ, ọpọlọpọ ero ni wọn ba niwaju ile iya wọn pẹlu awọn ọlọpaa lati tesan Fagun, l’Ondo.

Inu agbára ẹjẹ, nibi ti ọmọ Kalaba tuntun to ṣẹṣẹ gba bii ọmọ ọdọ fi ọbẹ dumbu rẹ si ni wọn ba iya wọn lẹyin ti wọn wọle.

Kẹmi ni awọn ba seeni ọrun ti ọmọ ọdọ yii maa n wọ sọrun lẹgbẹẹ oku iya awọn, bẹẹ lawọn tun ri ẹjẹ balabala lara firiiji, àga, irin ilewọ ti wọn fi n silẹkun yara rẹ ati ilẹ inu yara to n sun.

Ni kete to ti ṣiṣẹ ibi ọwọ rẹ tan lo ti sa lọ, gbogbo akitiyan awọn ọlọpaa lati ṣawari rẹ ko si ti i seso rere lasiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ti fi pampẹ ofin gbe ẹni to mu un waa ṣiṣẹ lọdọ Iya Kẹmi, tesan ọlọpaa Fagun lọkunrin ọhun si wa lọwọlọwọ nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.

Oku Iya Kẹmi ree ninu ile rẹ tí ọmọ Kalaba pa a si.

 

Leave a Reply