Lẹyin ọjọ marun-un lakata awọn ajinigbe, awọn ọmọ Ilọrin meji ti wọn ji gbe ni Suleja, gbominira 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Wọn ni ẹni ti yoo royin ogun ko ni i ku sogun, ọrọ yii gan-an lo ṣẹ mọ awọn ọmọ bibi ilu Ilọrin meji kan, Mubarak Idris ati Miudeen Sulyman, ti awọn ajigbe ji gbe lọna Kaduna/Suleja, ti wọn si wa lakata awọn ajinigbe fun ọjọ marun-un ti gbominira, wọn sọ ohun toju wọn ri lakata awọn ajinigbe ọhun.

Awọn mejeeji ti wọn ji gbe yii jẹ akẹkọọ ni Fasiti Ijọba apapọ to wa ni ilu Dutse, nipinlẹ Jigawa. Lasiko ti wọn n lọ siluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, ni awọn ajinigbe ji wọn pọ mọ awọn ero inu ọkọ ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ to kọja.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni wọn gbominira lẹyin ti wọn lo ọjọ marun-un gbako lakata awọn ajinigbe ọhun lẹyin ti wọn lu wọn bii aṣọ ofi tan.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ALAROYE, ṣe abẹwo si awọn mejeeji nileewosan kan ti wọn ti n gba itọju lagbegbe Gaa-Odota, niluu Ilọrin. Idris to sọrọ lorukọ awọn mejeeji sọ pe gbogbo ohun toju ri kọ ni ẹnu le sọ, ṣugbọn awọn dupẹ pe awọn ṣi tun wa laaye bayii.

Obi awọn akẹkọọ ọhun dupẹ lọwọ Gomina Abdulrazak fun akitiyan ati inawo ti wọn ṣe lati le ri awọn akẹkọọ naa gba lọwọ awọn ajinigbe. Bakan naa, wọn tun dupẹ lọwọ ẹgbẹ akẹkọọ ipinlẹ Kwara fun aduroti wọn ti wọn fi ri awọn ọmọ naa doola, wọn tun dupẹ lọwọ Ẹmia ilu Ilọrin, Ibrahim Zulu Gambari ati Imaamu agba, Mohammad Bashir, fun adura ati ipa ribiribi ti wọn ti wọn fi ri wọn doola kuro lọwọ awọn ajinigbe.

Leave a Reply