Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Wọn ni ẹni ti yoo royin ogun ko ni i ku sogun, ọrọ yii lo ṣẹ mọ awọn iyalọja mọkanla pẹlu ọmọọdun meji kan tawọn agbebọn ji gbe lona Àjàṣẹ́-Ìpo si Ọ̀kè-Ọdẹ, nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn, nipinlẹ Kwara, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ti wọn si wa lakata wọn fun ọjọ marun-un, ṣugbọn ti wọn gbominira laaarọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un yii.
ALAROYE gbọ pe awọn iyalọja ọhun ni wọn lọọ taja lọja ilu kan ti wọn n pe ni Òkè-Ọdẹ, nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn, nipinlẹ Kwara, ṣugbọn nigba ti wọn n dari pada ni nnkan bii aago mẹfa si meje alẹ, ni awọn agbebọn naa da wọn lọna, ti wọn si ko gbogbo wọn si inu igbo.
Lẹyin igbiyanju awọn ẹṣọ alaabo ọlọpaa ati fijilante ni wọn doola wọn lọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, DSP, Ejirẹ Adetoun Adeyẹmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa l’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un yii. O ni pẹlu akitiyan awọn ẹṣọ alaabo, iyẹn ọlọpaa ati fijilante, awọn ti doola awọn arinrin-ajo mejila kan ti wọn ji gbe lọna Àjàṣẹ́-Ìpo, si Òkè-Ọdẹ, nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn, nipinlẹ Kwara, wọn si ti darapọ mọ mọlẹbi wọn, ati pe wọn ti gbe awọn to fara pa lasiko ti wọn n doola wọn lọ sileewosan Jẹnẹra to wa niluu Shàrẹ́.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Victor Ọlaiya, ti ni gbogbo awọn to huwa ibajẹ naa ko ni i lọ lai jiya. Bakan naa lo rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ ọhun ki wọn maa wa ni oju lalakan fi n ṣọri, o ni ti wọn ba ṣakiyesi iwa aitọ lagbegbe wọn, ki wọn fi to awọn ẹṣọ alaabo leti.