Lẹyin ọjọ mẹrinla ti Alaafin waja, Onijẹru tilẹ Ijẹru naa tun papoda

Ọlawale Ajao, Ibadan
Nigba ti gbogbo ilẹ Yoruba ṣi n ṣọfọ ipapoda Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi to waja, Onijẹru tilẹ Ijẹru, Ọba Elijah Ọlaniyi Popoọla, naa ti tun darapọ mọ awọn baba nla rẹ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun 2022 yii, lọba to lo ọdun marundinlaaadọrun-un (85) laye naa dara pọ mọ awọn baba nla ẹ lẹyin ọjọ bii meloo kan to ti wa lori ailera to ni i ṣe pẹlu ogbo.
Ọdun mẹrinla lori ade naa lo nipo ọba, nitori lọdun 2008 lo gori itẹ.
Ilu Ijẹru, lo wa niluu Ogbomọṣọ, nijọba ibilẹ Guusu Ogbomọṣọ (Ogbomọṣọ South), nipinlẹ Ọyọ.
Ipapoda ọba yii waye lọjọ kẹrinla ti Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, wọ kaa ilẹ lọ.
Lati ọjọ ti iku ti mu Ọba Adeyẹmi re ibugbe ayeraye lawọn eeyan ti n pakiyesi ara wọn si bi iku awọn ori ade ṣe n waye leralera lẹnu lọọlọọ yii.

Laarin oṣu mẹfa sasiko yii, o kere tan, ọba meje lo ti waja nipinlẹ Ọyọ nikan ṣoṣo.
Onigbẹti tilu Igbẹti, Ọba Emmanuel Oyekan Oyebisi (Afasẹgbejo Kẹta), lo kọkọ rajo alọọde nipari ọdun to kọja, iyẹn lọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2021. Ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77) lo wa ti iku fi mu un lọ si isalu ọrun.
Oṣu kan ati ọjọ mẹfa pere sigba naa ni Ṣọun tilẹ Ogbomọṣọ, Ọba Jimoh Oyewumi (Ajagungbade Kẹta), tẹle e, lọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 2021 ọhun kan naa lọba nla Ogbomọṣọ waja.
Loru mọju ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun naa, ti i ṣe ọjọ kẹsan-an ti Ṣọun Ogbomọṣọ waja, l’Aṣigangan tilẹ Igangan, Ọba Abdul-Azeez Adeoye Lawuyi, naa tẹle e.
Bi ikede ipapoda awọn ọba alade ṣe pari ọdun 2021 nipinlẹ Ọyọ, bẹẹ naa ni irọkẹkẹ ijade laye awọn kabiesi bẹrẹ ọdun 2022 ta a wa yii. Titi di oṣu Karun-un, ọdun 2022 ta a wa yii, niroyin ipapoda awọn ọba wọnyi n gori afẹfẹ leralera wọn.
Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, lakọkọ ọba to waja lọdun 2022 yii. Lọjọ keji, oṣu Kin-in-ni, loun faye silẹ to gbọrun lọ lẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un (93).

Ko to oṣu kan lẹyin ti Olubadan di ara ilẹ ti Ọba Gabriel Adepọju ti i ṣe Oloko ti Oko-Ile, nijọba ibilẹ Oríire, nipinlẹ Ọyọ, naa dagbere faye, lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, loun lọọ dara pọ mọ awọn baba nla ẹ.
Nigba ti yoo fi to oṣu mẹta lẹyin eyi, opo tun yẹ laafin wọn niluu Ikoyi-Ile, nijọba ibilẹ Oriire, nigba ti iroyin tun gba aye kan pe Ọba Abdulyekeen Ayinla Oladipupọ ti i ṣe Onikoyi ti Ikoyi naa ti wa iwo ẹṣin lọ. Iṣẹlẹ eyi waye lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii.
Ọjọ kẹrindinlogun, si iṣẹlẹ Onikoyi l’Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, naa rinrin-ajo alọ-ide. Lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 tav a wa yii lọba to pataki aṣa ọhun rele lọọ sinmi.
Ọjọ kẹrinla, nigba ti gbogbo ilẹ Yoruba ṣi n ṣedaro ipẹyinda Ọba Adeyẹmi lọwọ l’Ọba Popoọla ti i ṣe Onijẹru tilẹ Ijẹru tun ṣe bẹẹ to rewalẹ aṣa.

Leave a Reply