Lẹyin ọjọ mẹrinlelaaadọfa, DSS tu awọn ọmọ Sunday Igboho yooku silẹ lahaamọ

Jọkẹ Amọri

Lẹyin ti awọn eeyan naa ti lo oṣu mẹrin, o din ọjọ diẹ latimọle ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, awọn eeyan naa ti tu awọn ọmọọṣẹ ajijagbara nni, Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti wọn fi pamọ si akata wọn latọjọ yii silẹ pe ki wọn maa lọ.

Ọjọ Eti, Furaidee, opin ọsẹ yii ni wọn tu awọn eeyan naa silẹ lẹyin ti wọn lo ọjọ mẹrinlelaaadọfa (114) lakata wọn.

Awọn eeyan ti wọn pada tu silẹ ọhun ni obinrin kan to maa n kọ ọrọ sori ẹrọ ayelujara ti orukọ rẹ n jẹ Amudat Babatunde ti gbogbo eeyan mọ si Lady K ati Jamiu Oyetunji.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, ni wọn ko awọn eeyan naa lasiko ti awọn ọtẹlẹmuyẹ naa ṣakọlu sile Sunday Igboho.

Bo tilẹ jẹ pe wọn pada gba beeli diẹ ninu wọn lẹyin ọpọlọpọ wahala latọdọ agbẹjọro wọn, sibẹ, wọn ko lati tu awọn meji yii silẹ, wọn ni wọn mọ nipa awọn nnkan ija oloro to wa nile Sunday Igboho.

Latigba naa ni Agbẹjọro wọn, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, atawọn mi-in ti wa lori ọrọ naa, ko too di pe wọn gba itusilẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Leave a Reply