Lẹyin ọjọ mẹsan-an, wọn tu awọn ọmọleewe ti wọn ji gbe nipinlẹ Niger silẹ

Faith Adebọla

 

 

 

Lẹyin tawọn ọmọleewe atawọn olukọ wọn tawọn janduku agbebọn kan ji gbe nileewe ijọba Government Science College, Kagara, nipinlẹ Niger, ti wa lahaamọ wọn fọjọ mẹsan-an gbako, wọn ti tu wọn silẹ.

Nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni wọn da awọn majeṣin naa silẹ lominira.

Ba a ṣe gbọ, mejidinlogoji ni gbogbo awọn ti wọn tu silẹ yii, awọn mẹrilelogun lara wọn ni ọmọleewe, tiṣa wọn lawọn mẹfa, nigba tawọn mẹjọ to ku jẹ mọlẹbi awọn tiṣa naa ti wọn jọ n gbe.

Bi wọn ṣe tu wọn silẹ, ọfiisi gomina ipinlẹ naa, Abubakar Sani Bello, ni wọn ko wọn lọ, ni Minna, olu-ilu ipinlẹ naa. Ibẹ ni gomina ti bẹ wọn pe ki wọn ma ṣe tori iṣẹlẹ aburu yii sọ p’awọn o ni i kawe mọ, o nijọba maa ṣeto to yẹ fun aabo wọn, tiru iṣẹlẹ bẹẹ ko fi tun ni i waye mọ.

O lawọn tun maa ri i pe gbogbo wọn ṣe ayẹwo to yẹ, wọn si ri itọju ilera gidi gba, tori ohun ti wọn la kọja lakata awọn janduku agbebọn naa.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji yii, lawọn kọlọransi ẹda naa ya bo ileewe awọn ogo wẹẹrẹ yii, wọn yinbọn pa ọmọleewe kan, wọn si ji awọn tọwọ wọn ba yii gbe, bẹẹ ni wọn ṣe ko wọn wọgbo lọ.

Leave a Reply