Lẹyin ọjọ mẹwaa to ti n gbaawẹ nitori ọkọ rẹ to file silẹ fọdun mẹrin, Joy ku si ṣọọṣi n’Ishẹri-Ọlọfin

Adefunkẹ Adebiyi

Obinrin kan, Joy Owoẹyẹ, ẹni ti ọkọ rẹ file silẹ latọdun kẹrin sẹyin lai wale, ti dagbere faye bayii. Aawẹ ọlọjọ mẹrinla ti wọn yan fun un ni ṣọọṣi, nitori ki ọkọ naa le pada wale lo n gba lọwọ to fi ku lọsẹ to kọja.

ALAROYE gbọ pe Ṣọọṣi CAC, Ori-Oke Gbogunmi ti wọn tun n pe ni Ajanpẹlẹnbẹ, n’Ishẹri-Ọlọfin, ni Joy ti lọọ gbadura, to si n wa nibẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ni ko duro si ṣọọṣi ọhun.

Ọjọ mẹrinla gbako ni wọn ni ko fi gbaawẹ ati adura ọhun, pẹlu ireti pe nigba ti yoo ba fi gba aawẹ naa tan, ọkọ rẹ ti ko boju wẹyin wo oun atọmọ yoo fẹsẹ ara rẹ rin wale waa ba a ni.

Eyi ni obinrin naa fi bẹrẹ aawẹ naa pẹlu adura, bi yoo ba si ṣinu, ki i jẹun. Omi ati oyin ti wọn ni ko maa fi ṣe ounjẹ naa ni yoo jẹ. Bo ṣe n jẹ kinni ọhun ree ti aawẹ fi pe ọjọ mẹwaa. Afi bo ṣe jẹ pe ọjọ kẹwaa naa ni nnkan yiwọ.

Pasitọ to wa ni ṣọọṣi naa, Alfred Sunday, ṣalaye pe niṣe ni Joy ko mọ ibi to wa mọ lọjọ ti aawẹ rẹ ku mẹrin ko fi tan yii. O ni ẹsẹkẹsẹ lawọn ti sare gbe e lọ si ọsibitu jẹnẹra Igando, ṣugbọn iku lo ja si.

Pasitọ Alfred sọ pe, ‘’Adura lo waa gba lọdọ wa, ko si nnkan kan ju bẹẹ lọ. Koda, a ṣe iṣọ oru, oun naa dẹ wa daadaa ba a ṣe n ṣe e, nnkan kan ko ṣe e nigba yẹn. Ọlọrun ni ẹlẹrii mi, ko si nnkan kan to pamọ lori iku rẹ yii, a o mọ nnkan kan nipa ẹ.

‘‘Nnkan bii aago meje aarọ lo ṣẹlẹ, ọmọ ẹ, Oluwatiṣe, naa wa nibẹ pẹlu ẹ. Emi tiẹ n gbadura lọwọ lori pẹpẹ ni, bi ọmọ ijọ kan ṣe waa pe mi niyẹn pe o ti daku.

‘’Nigba ti mo sun mọ ọn lati yẹ ẹ wo, mo ri i pe ko le da duro mọ. Mo pe e, o kan n da mi lohun lọna jinjin rere ni, ohun rẹ ko jade daadaa. A sare gbe e lọ si ọsibitu jẹnẹra Igando, ṣugbọn niṣe lo ku.’’

Pasitọ yii lọọ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn ni teṣan ọlọpaa, wọn si ti oun ati olori ṣọọṣi naa mọle fọjọ mẹta ki wọn too da wọn silẹ.

Awọn ẹbi Joy lawọn ko ṣẹjọ, wọn lawọn ti gba f’Ọlọrun. Awọn ara ṣọọṣi naa si lawọn ti yi ofin awọn pada lori ohun ti awọn to n gba aawẹ biribiri yoo fi maa ṣinu.

Wọn lawọn ti ṣofin pe ẹkọ mimu ni kẹni to ba gbaawẹ maa fi ṣinu bayii, ki i ṣe oyin ati omi mọ.

Wọn lẹni ti ko ba ti le tẹle ofin tuntun yii, awọn ko ni i jẹ ko gbaawẹ ni ṣọọṣi awọn mọ, nitori iku Joy Owoẹyẹ yii ti jẹ ẹkọ fawọn.

Leave a Reply