Lẹyin ọjọ mọkanlelogun, Ọọni fi oju ọmọ rẹ han faraye

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gẹgẹ bii ileri to ṣe pe lẹyin ọjọ mọkanlelogun loun yoo too fi oju ọmọ oun han fun gbogbo aye ri, Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, gba ọmọ rẹ, Tadenikawo Adesọji Aderẹmi, wọle saafin rẹ loni-in, o si ṣi oju ọmọ naa.

Ẹnu Gẹru to wa laafin ni wọn gbe Tadenikawo ati Olori Ṣilẹkunọla ti i ṣe iya rẹ gba, awọn Agba Ifẹ ti Ọbalufẹ, Ọba Idowu Adediwura ko sodi, awọn Modewa ti Lọwa Adimula, Oloye-agba Adeọla Adeyẹye dari ati awọn ẹmẹsẹ ti Sarun Oriowo Oyeyẹmi ko sodi, ni wọn gba wọn wọle.

Ninu Ile-nla ni wọn ti gbe Tadenikawo le Ọọni Ogunwusi, ẹni to gba inu Ile-Igbo jade, lọwọ, oun atawọn agbaagba kan si wọnu Ile-Igbo lati lọ wo ẹjẹ ọmọdekunrin naa gẹgẹ bii aṣa, pẹlu ẹrin ati ijo ni kabiesi si fi gbe ọmọ naa jade, to si gbe ọmọ naa le iya rẹ lọwọ.

Bayii ni oniruuru ayẹyẹ bẹrẹ, ti gbogbo awọn eeyan si n ki kabiesi ku oriire.

Leave a Reply