Lẹyin ọmọ marun-un, baba iyawo gb’ọmọ ẹ pada lọwọ ọkọ, o ni ko sanwo ori ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Baale ile to ko awọn ọmọ yika ara rẹ yii ko ri ọgbọn kankan da si ohun to n ṣẹlẹ si i lọwọlọwọ, baba obinrin to bi awọn ọmọ naa fun un lo gba ọmọ rẹ pada lọwọ ọkunrin yii. O ni nigba to kọ ti ko sanwo ori iyawo rẹ titi tọmọ fi pe marun-un, ko maa da tọju awọn ọmọ rẹ, ko ba oun mu ọmọ toun. N lo ba mu ọmọ rẹ lọ.

Laban Sabiti lorukọ ọkunrin yii, iyawo to bimọ marun-un fun un ni Prize Twikirize, orilẹ-ede Uganda ni wọn n gbe, labule Kirima, lagbegbe Bushuura.

Wọn ti n ba aye wọn bọ lai jẹ pe ọkọ sanwo ori, wọn si ṣe bẹẹ titi ti ọmọ fi pe marun-un, ki baba iyawo, Ọgbẹni Geoffrey Kakona, too yari laipẹ yii, to si waa mu ọmọ rẹ kuro nile ọkọ, to da awọn ọmọ maraarun silẹ fun baba wọn.

Eyi to dagba ju ninu awọn ọmọ yii jẹ ọmọ ọdun mẹwaa, kekere inu wọn ko si ju ọmọ ọdun kan ati oṣu kan lọ, o ṣi n muyan lọwọ ti baba iya rẹ fi ja a lẹnu ọmu, to mu iya rẹ lọ.

Ọkọ iyawo, Ọgbẹni Sabiti, ko mọ bi yoo ṣe yanju iṣoro to de ba a naa, niṣe lo ni ko dara bi baba iyawo oun ko ṣe ni suuru to. O ni Disẹmba, iyẹn oṣu kejila, ọdun yii, loun pinnu lati sanwo ori ọmọ rẹ, meloo naa lo si ku ki Disẹmba de, ti baba fi waa da ọmọ marun-un soun laya, to waa mu iyawo oun lọ.

Ni Sabiti ba kuku lọọ pe baba iyawo rẹ lẹjọ ni kootu, o lo fi ẹtọ oun du oun pẹlu ọmọ rẹ to mu lọ naa, o si fi ẹtọ awọn ọmọ naa du wọn nipa mimu iya wọn lọ, paapaa, eyi to ṣi n muyan lọwọ.

Loootọ, iwe ofin Uganda ti figba kan sọ pe dandan kọ ni owo ori obinrin fun ọkọ rẹ, wọn ni gbogbo ẹni to ba ti pe ọdun mejidinlogun ti le da ipinnu ṣe lori ẹni to ba wu u lati fẹ, baba iyawo kan ko lẹtọọ lati maa beere fun owo-ori bo ti wu ko kere mọ.

Ṣugbọn lọdun 2017, iru ẹjọ bayii waye, ile-ẹjọ kan to gbọ ọ si sọ pe ori aṣa ni igbeyawo duro le, ki i ṣe ofin ijọba. Wọn ni ẹtọ ni fun ọkọ iyawo lati sanwo ori obinrin to fẹẹ fẹ fawọn obi rẹ, gbogbo aṣa ka maa da owo-ori pada fun idile ọkọ lẹyin ti wọn ba san an lọjọ igbeyawo ko tọna rara.

Sabiti ati baba iyawo rẹ ṣi wa lẹnu tiwọn yii naa o, wọn ko ti i mọ ẹni tile-ẹjọ yoo da lare.

Leave a Reply