Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Mariam Akinkitan lorukọ obinrin to tẹ ọmọ mẹrin tira yii, o ṣẹṣẹ bi wọn ni. Ko niṣẹ kankan lọwọ, Samson Akinkitan, ọkọ ẹ, to n ṣiṣẹ telọ lo n gbọ bukaata lori ẹ ati ọmọ meji ti wọn ti bi tẹlẹ, ki oore ọtun to ka wọn laya yii too tun wọle de laipẹ yii ni Badagary ti wọn n gbe.
Ibi kan ti wọn n pe ni Iyana-Ira, lawọn tọkọ-taya yii n gbe, yara kan ṣoṣo naa ni wọn gba ti tọkọ-tiyawo pẹlu awọn ọmọ meji ati iya ọkọ paapaa n gbe. Ṣugbọn nigba ti Ọlọrun yoo gbe iṣe rẹ de, Mariam, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), loyun mi-in, nigba ti yoo bimọ ọhun ni agbara wọn ko ka a lọsibitu aladaani ti wọn kọkọ gbe e lọ.
O ti bi ọkan ninu awọn ọmọ naa si ọsibitu aladaani yii, n lo ba di pe ko ri awọn yooku bi mọ, bẹẹ, kedere lo han si wọn lọsibitu naa pe ọmọ to wa ninu obinrin yii ki i ṣe ẹyọ kan, koda ki i ṣe meji. Nigba ti agbara wọn ko ka a mọ ni wọn ni ki ọkọ rẹ waa maa gbe e lọ, ibẹ lo gba de Ajara Medical Centre, ni Badagry.
Dokita Dauda Bioku to gbẹbi fun un ṣalaye fun Ajọ Akọroyinjọ ilẹ Naijiria (NAN), pe iya ikoko naa ko le da awọn ọmọ to wa ninu rẹ bi mọ, bo tilẹ jẹ pe funra ẹ lo bi eyi ti wọn kọkọ gbẹbi ẹ ni ọsibitu aladaani yẹn.
Dokita Bioku sọ pe ọwọ ti awọn ọmọ to ṣẹku sinu rẹ naa n gbe bọ lagbara, beeyan ko ba si fẹẹ padanu iya atawọn ọmọ naa, afi ko ṣiṣẹ abẹ. O ni nitori eyi lawọn ṣe ṣiṣẹ abẹ fun Mariam Akinkitan, tawọn ṣe bẹẹ gbe ọmọ mẹta jade ninu rẹ, awọn ọmọ naa si jẹ mẹrin, obinrin mẹta, ọkunrin kan.
Bi wọn ṣe waa gbohun iya ti wọn gbọ ti awọn ọmọ tan, ironu lo ku to dori agba Samson to jẹ baba awọn ọmọ naa kodo. Ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji (35) naa bẹrẹ si i rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria ni, ati ijọba.
Samson sọ pe iṣẹ telọ toun n ṣe ko mu owo pupọ wale, iyẹn loun ko ṣe le gba ju yara kan lọ. O ni ninu yara kan naa ni oun, iyawo, ọmọ meji tọjọ ori wọn jẹ mẹfa ati mẹta pẹlu mama oun n gbe. Awọn marun-un ti wa ninu yara tẹlẹ kawọn oore tuntun yii too tun de bayii, oun yoo ha tun ko awọn ẹjẹ ọrun naa sinu yara yii bi? Awọn yoo waa di mẹsan-an ninu yara kan ṣoṣo.
O tun ni aisowo ni ko jẹ koun kawe si i, to jẹ iṣẹ telọ loun kọ. O loun ko fẹ kiru ẹ jẹ ipin awọn ọmọ oun wọnyi, kawọn eeyan ṣaanu oun.
Fun idi eyi lo ṣe n rawọ ẹbẹ sawọn eeyan ti Ọlọrun ba bukun, to si fi omi aanu si loju, pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn ma jẹ koun ko awọn ikoko yii lọ sile tawọn n gbe naa. O ni ki wọn ṣaanu oun pẹlu ibugbe tuntun ati ọna iranwọ mi-in ti oun yoo fi gbọ bukaata oore gbankọgbii ti Ọlọrun ṣe foun yii.