Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye, Ọmọdewu di alaga APC ipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Kọmiṣanna tẹlẹ fọrọ ilẹ ati eto ilegbee nipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Isaac Ajiboye Ọmọdewu, ti di alaga titun fẹgbẹ oṣelu All Progessives Congress (APC) ipinlẹ naa ninu eto idibo ẹgbẹ ọhun to waye lọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 ti i ṣe ọjọ Àbámẹ́ta, Satide, opin ọsẹ yii.

Igba meji ọtọọtọ lo yẹ ki eto yii ti waye sẹyin, ṣugbọn ti wọn n yẹ ẹ nitori ọpọlọpọ ija ati atako to ti waye lori eto idibo naa ṣaaju. Ija ọhún sí lè to bẹẹ ti alaga ati akọwe ẹgbẹ ọhún ti wọn ṣẹṣẹ fi ipo silẹ ko gbọ ara wọn ye mọ, to jẹ pe kaluku lo n ṣe tiẹ lọtọọtọ lati ri i pe ọmọ oye toun lẹgbẹ dibo yan sipo.

Ki wọn too papa ri ibo ọhun di lọjọ Abamẹta naa nkọ, ọpọlọpọ wakati lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tinu n bi fi lọọ gbeja ka Alhaji Gambo Lawan ti i ṣe alaga igbimọ to ṣakoso eto idibo naa mọ ileeetura to de si, ọsan gangan ni wọn too ribo ọhun di lẹyin ti ọkunrin naa too ra pala jade kuro nileetura naa.

Lara awuyewuye to tidi eto ọhun suyọ ni bi diẹ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ yii ṣe n naka aleebu si awọn agba ẹgbẹ ọhun meji kan, Ọtunba Adebayọ Alao-Akala ati aṣofin agba to n ṣoju ẹkun idibo Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ yii niluu Abuja,

Sẹnetọ Teslim Fọlarin, wọn ni wọn n wọna lati fi tipatipa yan  awọn adari ẹgbẹ le awọn lori.

Eto ti Ọtunba Akala to jẹ alaga igbimọ oludamọran fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ ọhun ṣe ni lati jẹ ki alaga tuntun fẹgbẹ naa wa lati agbegbe Oke-Ogun.

Ninu awọn ọmọ Oke-Ogun to n dupo naa ni Ọgbẹni Abu Gbadamọsi, Isaac Ọmọdewu, Dele Akinlẹyẹ ati Ọgbẹni Abọlade.

Ni nnkan bii ọjọ mẹta ṣaaju idibo ọhun nigbimọ yii ti gba awọn adari ẹgbẹ nimọran lati lọọ forikori lati fa ọkan ninu awọn ara Oke-Ogun to n dupo alaga ẹgbẹ naa silẹ, ki wọn si panu-pọ yan an sipo naa lai dibo rara.

Niṣe ni minisita feto ibanisọrọ nilẹ yii nigba kan, Amofin Adebayọ Shittu, tiẹ gbena woju Ọtunba Akala ati Sẹnetọ Fọlarin ni tiẹ, o ni wọn ko kunju oṣunwọn lati ya afọbajẹ kalẹ sinu ẹgbẹ APC pẹlu bo ṣe jẹ pe wọn ko si lara awọn to jiya ẹgbẹ naa latilẹ, nitori ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn n ṣe tẹlẹ ki wọn too dara pọ mọ APC nigba ti nnkan ṣẹnuure fẹgbẹ oṣelu ọhun tan.

Ṣugbọn ifẹ ọkan Ọtunba Akala atawọn ẹmẹwa ẹ lo pada ṣẹ pẹlu bi Ọnarebu Ọmọdewu ti wọn papa dibo yan sipo ọhun ṣe jẹ ọmọ bibi ilu Otu, nijọba ibilẹ Itẹsiwaju, lagbegbe Oke-Ogun.

Yiyan naa ni wọn pada yan alaga naa pẹlu gbogbo igbimọ iṣakoso ẹgbẹ ọhun ni papa iṣere nla Ọbafẹmi Awolọwọ to wa lagbegbe Oke-Ado n’Ibadan.

Lẹyin eto naa l’Ọnarebu Ọmọdewu ti i ṣe alaga ẹgbẹ APC tutun naa ṣeleri lati pẹtu si gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tinu n bi ninu lati ri i pe ẹgbẹ oṣelu naa ṣaṣeyọri ninu awọn idibo gbogbogboo ọjọ iwaju gbogbo ni ipinlẹ naa.

Leave a Reply