Lẹyin ọpọlọpọ miliọnu, awọn Fulani ti tu alaga ijọba ibilẹ Iganna ti wọn gbe silẹ

Aderohunmu Kazeem

Awọn Fulani ti tu alaga ijọba ibile Onidagbasoke Iganna, Ọgbẹni Jacob Ọlayiwọla Adeleke, silẹ lẹyin ti wọn gbowo, ti wọn tun fiya nla jẹ ẹ

Ọjọ Abamẹta, Satide,  lawọn Fulani ajinigbe tu alaga ọhun ati dẹrẹba ẹ ti wọn ji gbe silẹ, lẹyin ti wọn ti lo ọjọ marun-un lọdọ wọn.

Ilu Ibadan ni Adeleke n lọ ki wọn too ji awọn mejeeji gbe lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii.

ALAROYE gbọ pe, deede aago mẹfa irọlẹ ana ni wọn ri alaga kansu ọhun ati dẹrẹba ẹ ti wọn pe ni Mufu gba pada, lẹyin tawọn Fulani yii ti bii miliọnu marun-un aabọ lọwọ awọn eeyan wọn.

Ọkan ninu awọn eeyan agbegbe ọhun to ba wa sọrọ, ṣugbọn to kọ lati darukọ ara ẹ sọ pe awọn Fulani ni wọn ji ọkunrin oloṣelu naa gbe, ati pe ori oke kan ni wọn gbe wọn lọ lagbegbe Ado-Awaye mọ Iṣẹyin. O ni awọn janduku ọhun ko duro soju kan, niṣe ni wọn n rin kiri, ti wọn si fiya jẹ alaga yii pẹlu ẹni keji ẹ.

Alaga kansu Iwajọwa, Ọnarebu Akeem Adedibu, ni wọn sọ pe o lọọ gbe alaga ọhun wa ni kete ti wọn tu u silẹ. Bakan naa la gbọ pe awọn ajinigbe yii to meje.

Wọn ni ọkunrin oloṣelu yii ti pinnu lati lọọ gba itọju lọsibitu, ki ara ẹ le bọ sipo lẹyin idaamu tawọn Fulani ajinigbe ko ba a.

Tẹ o ba gbagbe, igba miliọnu naira lawọn ajinigbe ọhun lawọn fẹẹ gba nigba ti wọn kọkọ ba awọn eeyan Ogbẹni Jacob Ọlayiwọla Adeleke sọrọ lẹyin ti wọn ji i.

Ilu Ilua, ni wọn ti kọ lu oun ati dẹrẹba ẹ laarin Ado-Awaye si Okeho. Wọn ni gbogbo igba nirufẹ iṣẹlẹ bẹẹ maa n waye laarin Ado-Awaye, Iganna, Okeho atawọn ibomi-in to sun mọ ọn

Leave a Reply