Adewumi Adegoke
Beeyan ba gun ẹṣin ninu agba onifuji ilẹ wa to gbajumọ daadaa nni, Sheed Akorede ti gbogbo eeyan mọ si Saidi Osupa, ko ni i kọsẹ rara. Eyi ko sẹyin bi wọn ṣe fun un ni fisa ilu oyinbo to ti n wa tipe, to si wa niluu Amẹrika di ba a ṣe n sọ yii, nibi to ti n forin da aọn ololufẹ rẹ laraya.
Ki i ṣe pe oṣere naa ṣẹṣẹ n lọ siluu oyinbo, o ti lọ sawọn orileede kaakiri, bẹẹ lo ti figba kan gbe orileede Amẹrika naa ko too pada wa si Naijiria. Ṣugbọn awọn to sun mọ ọn sọ fun AKEDE AGBAYE pe o ni iṣoro ranpẹ nigba to wa ni Amẹrika lori ọrọ iwe rẹ ni, ki i ṣe pe o gbe oogun oloro tabi pe o jale lọhun-un o. Eyi lo fa a to fi jẹ pe ko le pada si orileede Amẹrika latigba naa. O ti le ni ọdun mẹwaa ti ọkunrin naa ti tẹ Amẹrika gbẹyin, bo tile jẹ pe o n lọ si awọn orileede mi-in kaakiri.
Ọpọ eeyan lo tiẹ ti fi akọrin Fuji naa ṣe yẹyẹ pe ko to ẹru to n de Amẹrika mọ, wọn ni to ba to bẹẹ ko tẹ baaluu leti, ko sọ pe oun n lọ sọhun-un. Ṣugbọn orin ni Saidi fi n da wọn lohun ni gbogbo igba naa pe, ‘Ẹ ṣaa mọ pe Amẹrika ti mo kọkọ lọ, mo lọọ towe mi ni, a ṣe pe erinmọje mi Baba Akiimu mi, to ba ya mi ti mo ba n ṣe faaji mi, mo maa lọ si Amẹrika bii ẹni to n lọ si Bariga ni. Gbogbo itukutu ti wọn n tu yẹn, bulṣiiti ni.’
Lọsẹ to kọja ni Saidi Oṣupa balẹ si Washington. Ori Instagraamu rẹ lo ti kọkọ kọ ọrọ naa si pe ‘‘Ọlọrun yoo ṣilẹkun ti ẹnikẹni ko le ti fun ẹ. Alhamdulilahi! Ọba orin ti pada si adugbo ẹ.’’
Leyin eyi lo gbe fidio kan jade, nibi to ti fi kọrin pe, ‘’Olulana lo ba mi ṣe ẹ ba mi dupẹ, ohun taye ro pe ninu aye mi ko le ṣe. Mo kọrin, bi ilẹkun ti pa, bi ilẹkun o ṣi. Bi ilẹkun ba fọdun ẹgbẹrun ti, ko na Ọlọrun Ọba ni wahala ju aṣẹ lọ. Ọba onimajẹmu ni ki i ṣé, Olulana Ọba Ọba adehun, ki i doju ti ẹni to gbagbọ ninu ẹ tọkan-tara.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ ni wọn lọọ pade rẹ ni Washington to balẹ si, ti wọn ko si le pa idunnu wọn mọra nigba ti wọn ri i ni orileede Amẹrika. Niṣe ni wọn n ṣe fidio loriṣiiriṣii pẹlu rẹ, ti wọn si n pariwo pe Saidi ti balẹ gudẹ si Amẹrika, bẹẹ loun naa n kọrin loriṣiiriṣii fun wọn.
Niṣe ni ori Instagraamu rẹ kun pẹlu ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti wọn n ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ilẹkun tuntun to ṣi fun un yii. Ọpọlọpọ awọn oṣere bii Kẹmi Korede, Muyideen Ọladapọ, Wale Okunnu, Iya Ibadan ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn n ba oṣere Fuji yii dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oore to ṣe yii.
Ọkan ninu awọn to sọrọ nipa irinajo Saidi yii ni Muyideen Ọladapọ ti gbogbo eeyan n pe ni Lala. O ni ‘’Mi o ni i sọ ọrọ kankan, ibi ti wọn ba ti ro wi pe o yẹ ki n sọrọ, Jagunjagun ni ẹ.’’ Oju-ẹsẹ ti Lala sọrọ yii ni Saidi naa da a lohun pe ‘Wa a ṣere, ma sọrọ kankan oooo. A dupẹ fun Ọlọrun’’
Kaakiri awọn ilu bii Los Angelis, Houston, Maryland, New York, Philadephia, Chicago, Miami ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ireti wa pe Saidi yoo gbe orin rẹ de ninu oṣu kẹfa ati Keje ọdun yii lorileede Amẹrika.