Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkan ninu awọn adari ipolongo ibo fun Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ All Progressive Congress to kọja yii, Ọgbẹni Alaba Abe, ni wọn ti yinbọn pa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ta a wa yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati inu atẹjade kan ti adari apapọ ẹgbẹ to n polongo ibo fun Ayedatiwa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Kayọde Fasua, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.
Abe to jẹ adari ipolongo ibo fun Ayedatiwa ni Wọọdu kẹwaa, niluu Ṣúpárè Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, lo ni wọn pa siwaju ile rẹ niluu Ṣúpárè, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ naa.
O ni Abe yii tun jẹ ọkan pataki ninu awọn ti ẹgbẹ APC yan lati ṣeto idibo abẹle ọhun ninu eyi ti ọga awọn, Ọnarebu Lucky Ayedatiwa ti wọle. Fasua ni titi di asiko yii lọrọ iku Abe ṣi n ya awọn lẹnu, nitori eeyan jẹẹjẹ kan ti ki i ba ẹnikẹni ja ni awọn mọ ọn si.
Idi niyi to ni awọn fi n rọ ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ẹsọ alaabo t’ọrọ kan lati tete ti ẹsẹ bọ iwadii iṣẹlẹ naa, ki wọn si ri i daju pe awọn fi pampẹ ofin gbe gbogbo awọn ti wọn ba lọwọ ninu iku rẹ, ki wọn le jiya to tọ labẹ ofin.