Lẹyin ọsẹ meji tawọn meji ku, kọntena tun ja bọ lu eeyan meji ni Ijeṣha

Faith Adebọla

Ko ti i pe oṣu kan ti awọn meji kan ku lojiji pẹlu bi kọntena ṣe ja lu ọkọ ti wọn wa ninu rẹ lori. Iru iṣẹlẹ buruku yii naa lo tun waye pẹlu bi kọntena mi-in tun ṣe ja bọ lẹyin ọkọ tirela ti wọn so o mọ, to si ti ran awọn obinrin meji kan lọ sọrun apapandodo lagbegbe Ijẹsha, loju ọna marosẹ Oṣodi si Apapa, nipinlẹ Eko.

Nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, niṣẹlẹ naa waye nibudoko Odo Olowu.

Ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo (LASEMA), Dokita Olufẹmi Ọkẹ-Ọsanyintolu ṣalaye pe ọkọ ajagbe naa ṣadeede padanu bireeki rẹ lojiji ni, ori ere lo si wa, bo ṣe di pe o lọọ fori sọ ọkọ ajagbe mi-in ti wọn paaki sẹbaa ọna tẹlẹ niyẹn, ni kọntena to wa lẹyin rẹ ba re bọ.

Olufẹmi ni ẹsẹkẹsẹ lawọn obinrin agbalagba meji ti doloogbe, tori kongẹ ori wọn ni kinni ọhun ja bọ le, bẹẹ lawakọ tirela naa ko raaye jade niwaju ọkọ, afigba tawọn oṣiṣẹ ajọ LASEMA naa de ti wọn ṣa ilẹkun ọkọ naa lo too le jade, o si ti fara pa yannayanna.

O ni titi di ba a ṣe n sọ yii, ko ti i si mọlẹbi awọn oloogbe naa to yọju, awọn ko si mọ orukọ tabi adirẹsi wọn, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ eleto ilera alagbeeka, SHEMU, ti gbe oku wọn lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa nitosi, bẹẹ ni awakọ naa wa nibi to ti n gba itọju pajawiri lọwọ.

Tẹ o ba gbagbe, iru ijamba yii kan naa waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, to kọja yii, nigba ti tirela kan lọọ kọlu bọọsi akero kan, ti kọntena ẹyin tirela naa si ja bọ lu bọọsi ọhun mọlẹ. Eeyan meji, Omidan Chidinma Ajoku ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Chima Nnaekpe, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, tawọn mejeeji jẹ oṣiṣẹ ajọ to n ri si papakọ ofurufu ilẹ wa, (Federal Airports Authority of Nigeria, FAAN), lo dagbere faye loju ẹsẹ, ti ẹni kẹta si ku si ọsibitu lẹyin ọjọ meji, yatọ si ọpọ to fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii.

Ọsẹ kan lẹyin iyẹn, lọjọ kin-in-ni, oṣu yii, lagbegbe Ilasamaja, loju ọna marosẹ Apapa si Oṣodi yii kan naa ni kọntena mi-in tun ti re bọ lori ere lẹyin tirela to gbe e, eeyan meji niyẹn naa tun sọ doloogbe lai ro tẹlẹ.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, ni Kọmiṣanna ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, kede pe awọn ti fi pampẹ ofin gbe awakọ ati ẹni to ni tirela to pa awọn oṣiṣẹ FAAN meji naa, awọn yoo si  ba wọn ṣẹjọ gẹgẹ bi Gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu, ṣe ṣeleri fawọn mọlẹbi oloogbe naa nigba to ṣabẹwo ibanikẹdun si wọn.

Leave a Reply