Lẹyin tawọn adigunjale gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira lọwọ oniPOS ni wọn yinbọn pa a n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn adigunjale ṣe bẹbẹ n’Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja pẹlu bi wọn ṣe da ọkunrin kan, Adebayọ Adekunle, ẹni to n ṣokowo olowogbowo (POS), lọna, ti wọn si gbowo ọwọ ẹ lẹyin ti wọn yinbọn pa a tan.

Ọkunrin kan to pera ẹ ni Mr Bhadoosky lo ṣalaye bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye faye gbọ.

Gẹgẹ bo ṣe kọ ọ si ikanni ayelujara rẹ, “A ti padanu ọdọmọkunrin kan ni nnkan bii wakati diẹ si asiko ti mo n sọrọ yii. Ẹṣẹ kan ṣoṣo to ṣẹ awọn to pa a ni pe o n tiraka wa ọna atijẹ atimu ara rẹ pẹlu iṣẹ POS to yan laayo.

“Lẹyin to gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira (₦800,000) to fẹẹ fi ṣowo POS fawọn onibaara rẹ tan nileefowopamọ, lawọn adigunjale yẹn da a lọna, ti wọn yinbọn mọ ọn, ti wọn si gba owo to ṣẹṣẹ gba ni banki yẹn lọwọ ẹ.

“Wọn gbe e lọ sọsibitu, awọn dokita ṣiṣẹ abẹ lati yọ ọta ibọn kuro lara ẹ, ṣugbọn wọn da iṣẹ abẹ naa duro laarin kan nitori pe awọn ẹbi Adekunle ko rowo iṣẹ abẹ ti awọn dokita beere san.”

Obinrin kan to pera ẹ ni aburo Oloogbe naa ṣugbọn ti ko darukọ ara ẹ, ṣalaye pe “Ori ọkada ni bọọda mi wa lẹyin to gbowo ni banki. Awọn ole da a lọna, ọpọlọpọ igba ni wọn yinbọn mọ ọn nitori awọn ibọn ti wọn yin ko tete ba a.
“Ọta ibọn pada ba a nikun ati lori. Wọn sare gbe e lọ sileewosan aladaani kan to wa lọna Mọlete, n’Ibadan, lọjọ Tusidee yẹn. Dokita si ni ki wọn mu miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira (₦1.7m) wa ki awọn fi ṣiṣẹ abẹ lati yọ awọn ọta ibọn to ko si wọn lara.

“A bẹ awọn dokita nitori a ko lowo to tọ bẹẹ yẹn lọwọ rara. Wọn ṣaa gba, wọn ṣiṣẹ abẹ, wọn si yọ ọta to ko sinu ikun wọn. Wọn ni ọta ti ba ifun bọda mi jẹ ati pe wiwa laaye wọn, ọwọ Ọlọrun nikan lo wa.
“Ṣugbọn a dupẹ pe iṣẹ abẹ yẹn kẹsẹ jari. Ṣugbọn nigba ta a beere pe ọta ti wọn sọ pe o ko si wọn ninu ori n kọ, wọn ni bi awọn ba maa ṣe iyẹn, ọ kere tan, a ni lati san miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (₦1.2m).

“Ori ibi ta a ti n wa owo yẹn kiri ni bọda mi ku si”.

Ọdọmọkunrin yii ko lo ju ọjọ meje lọ nileewosan naa tiku fi pa a nibi ti awọn ẹbi ẹ ti n lakaka lati wa owo iṣẹ abẹ.

Leave a Reply