Lẹyin tawọn agbanipa yinbọn pa kọmiṣanna yii tan ni wọn gbe oku ẹ sileegbọnsẹ ile e

Faith Adebọla

Kọmiṣanna fun imọ ijinlẹ ati imọ ẹrọ nipinlẹ Katsina, Ọmọwe Rabe Nasir, ti doloogbe, awọn agbanipa la gbọ pe wọn pa a.

Iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ Ọjọruu, ọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla yii. Wọn lọkunrin naa ṣẹṣẹ kirun tan ni ile rẹ to wa ni Fatima Shehu Estate, niluu Katsina ni. Bo ṣe n jokoo si palọ rẹ ni wọn yọ si i lojiji, ti wọn si yinbọn pa a.

Gẹgẹ bii iwadii tawọn ọlọpaa ṣe, wọn ni lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn gbe oku rẹ lọ sinu ile igbọnsẹ to wa lẹgbẹẹ palọ naa, wọn si tilẹkun mọ ọn sibẹ. Wọn lawọn ri ipa ẹjẹ lori aga ti wọn pa a si titi de tọilẹẹti ti wọn wọ ọ ju si.

A gbọ pe niṣe lawọn ọtẹlẹmuyẹ ja ilẹkun tọilẹẹti naa, Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn too ri oku rẹ gbe jade.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Katsina, CP Sanusi Baba, sọ fun ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), pe lẹyin ti wọn ti kọkọ yinbọn mọ oloogbe naa ni wọn tun fọbẹ gun un nikun kaakiri.

O lawọn ko ti i ri ẹnikan mu lori iṣẹlẹ yii.

Ẹnikan ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ fawọn oniroyin pe ki i ṣe awọn agbebọn lo ṣiṣẹ naa, awọn alagbapa lo maa jẹ, tori bi wọn ṣe gbe oku naa lọ sileegbọnsẹ ati bi wọn ṣe tun fọbẹ gun un lẹyin ti wọn ti yinbọn pa a ki i ṣe bi awọn agbebọn ṣe n ṣe.

Kọmiṣanna ọlọpaa lawọn agbofinro ti n ba iwadii lọ lori iṣẹlẹ yii, wọn si ti gbe oku ọkunrin naa lọ sọsibitu fun ayẹwo.

Ẹni ọdun mọkanlelọgọta (61) ni oloogbe naa, ọkan lara awọn Ọnarebu nileegbimọ aṣoju-ṣofin apapọ ni tẹlẹ, o si ti wa nipo oludamọran pataki si Gomina Aminu Masari tipinlẹ Katsina, ki wọn too yan an sipo kọmiṣanna yii.

Leave a Reply