Lẹyin tawọn Fulani fi maaluu jẹ oko Rilwan tan ni wọn tun ṣa a pa l’Odo-Ọtin

Florence Babaṣọla

Inu aibalẹ aya lawọn eeyan ilu Ijabẹ, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, nipinlẹ Ọṣun, wa bayii, pẹlu bi awọn Fulani bororo ṣe pa Ridwan, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Rado.

Laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, la gbọ pe awọn Fulani naa da maaluu wọn lọ sibi oko Ridwan to wa labule Bọọlẹ, nitosi Ijabẹ, ti wọn si ba oko naa jẹ gidigidi.

 

Eleyii lo bi Ridwan ninu to fi sọrọ, ọrọ to sọ lo di ija, wọn n ja lọwọ ni ọkan lara awọn Fulani naa fa ada yọ, to si ṣa Ridwan pa sinu oko rẹ.

 

Kia niroyin naa ti kan de aarin ilu, bẹẹ lawọn ọdọ atawọn eeyan agboole Eesa ti Ridwan ti wa ya lọ si oko naa, wọn si mu Fulani to ṣa Ridwan pa ati awọn meji miin.

 

A gbọ pe awọn agbaagba ni wọn pẹtu sawọn ọdọ naa ninu ti wọn ko fi gbẹsan lọwọ ara wọn. Aafin ọba ilu Ijabẹ ni wọn kọkọ ko wọn lọ, ko too di pe wọn fa wọn le ọlọpaa agbegbe naa lọwọ, ti awọn ọlọpaa si lọ gbe oku oloogbe naa kuro nibẹ.

 

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ ni Ridwan dero ọrun nibi iṣẹlẹ naa, ati pe iwadii n lọ lọwọ lori ẹ.

Leave a Reply