Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹsan-an yii, ni ọwọ ọlọpaa ba Abu Adamu ati Muhammadu Aliyu tawọn mejeeji jẹ Fulani darandaran. Inu igbo kan l’Ewekoro, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti mu wọn lẹyin ti wọn ni wọn ja idile kan lole owo, ti wọn tun mu ọmọ awọn ẹbi naa, ọmọ ọdun mẹrindinlogun lọ sinu oko paki, ti wọn si fipa ba a lo pọ.
Oru lawọn Fulani yii wọnu ile obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Aminat Okeshọla. Abule Afowowa Gbelu, l’Ewekoro, ni iya naa n gbe pẹlu ọmọ ẹ obinrin tawọn Fulani naa ba lo pọ yii.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ yii, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe awọn Fulani naa ti maa n da maaluu wọn kọja lojumọmọ labule naa tẹlẹ, awọn ara abule si mọ wọn daadaa.
Ṣugbọn ni nnkan bii aago kan oru ni wọn ya wọ ile Arabinrin Okeshọla gẹgẹ bo ṣe wi, wọn dira ogun wa, wọn si bẹrẹ si i daamu iya naa ati ọmọ ẹ, awọn mẹta ni wọn wa.
Ẹgbẹrun lọna ogoje naira (140,000)ni wọn digun gba lọwọ iya yii, lẹyin naa ni wọn mu ọmọ rẹ obinrin, ẹni ọdun mẹrindinlogun, lọ sinu oko paki iya rẹ, awọn mẹtẹẹta si ba a laṣepọ nikọọkan.
Bi wọn ṣe n huwa laabi ọhun lọwọ lawọn kan fi ipe ranṣẹ si teṣan ọlọpaa Ewekoro, awọn iyẹn si wa, wọn bẹrẹ si i wa awọn Fulani naa kiri inu igbo yii. Nibi ti wọn ti n wa wọn ni wọn ti ri awọn meji yii, Abu Adamu ati Muhammed Aliyu, ẹni kẹta wọn ni wọn ko ri mu.
Bi wọn ṣe mu awọn meji yii naa ni obinrin ti wọn ja lole atọmọ ti wọn ba sun ti naka si wọn pe awọn ni wọn ko ogun waa ja awọn, ti wọn gbowo lọ, ti wọn si tun ba ọmọdebinrin naa sun.
Awọn mejeeji tọwọ ba yii ti wa lọdọ ẹka SCID to n tọpinpin iwa ọdaran, CP Edward Ajogun si ti paṣẹ pe ki wọn wa ẹni kẹta wọn naa lawaari, koun naa le ba wọn jẹjọ idigunjale ati ifipabanilopọ ti wọn yoo ro ni kootu laipẹ