Lẹyin tawọn meje ti lọ, sẹnetọ mejidinlogun tun fẹẹ binu kuro lẹgbẹ oṣelu APC

Faith Adebọla

Ko din ni wakati meji gbako ti Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Sẹnetọ Abdullahi Adamu fi tilẹkun mọri ṣepade aṣelaagun pẹlu awọn sẹnetọ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa nileegbimọ aṣofin agba, l’Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa yii.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn sẹnetọ mejidinlogun mi-in ṣe faake kọri pe awọn ti ṣetan lati da igbalẹ ẹgbẹ APC to wa lọwọ awọn jọ, o si ṣee ṣe kawọn bẹrẹ si i ga aburada ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), tabi ki awọn sọda sinu ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party (NNPP).

Ṣe laipẹ yii, lọjọ Tusidee to ṣaaju, ni olori awọn aṣofin agba ọhun ka lẹta nipa awọn ṣenetọ meje ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn lawọn o ṣẹgbẹ naa mọ, ti wọn si ya lọ sinu awọn ẹgbẹ mi-in, setiigbọ awọn aṣofin ọhun.

Awọn sẹnetọ meje to dagbere fẹgbẹ APC naa ni Yahaya Abdullahi, Adamu Aliero, Ahmad Baba-Kaital, Haliru Jika, Francis Alimikhena, Ibrahim Shekarau ati Lawal Yahaya Gumau.

Eyi lo mu ki Adamu ati olori awọn aṣofin naa, Ahmed Lawan, wọle ipade pajawiri nigba ti olobo tun ta wọn pe awọn sẹnetọ mejidinlogun ti n palẹ ẹru wọn mọ lati ya kuro ni APC. Lara awọn ijoye apapọ ẹgbẹ APC to wa nipade naa ni Akọwe ẹgbẹ wọn, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, Igbakeji Alaga apapọ, Sẹnetọ Abubakar Kyari.

Nipade ọhun, ba a ṣe gbọ, awọn sẹnetọ to fajuro naa sọ pe lajori ohun to n bi awọn ninu ni abajade eto idibo abẹle sipo sẹnetọ to waye laipẹ yii ninu ẹgbẹ APC, eyi ti ifa rẹ ko fọ’re fun ọpọ ninu awọn aṣofin kaakiri orileede wa.

Awọn aṣofin naa fẹsun kan awọn gomina ipinlẹ koowa wọn pe wọn ṣojooro lasiko eto idibo abẹle, wọn ni ọpọ ibi ni wọn ti kuna lati tẹle ilana ati alakalẹ ẹgbẹ APC ati ofin eto idibo, ati bi ẹgbẹ naa ṣe kuna lati da awọn aṣofin to niriiri, ti wọn si n ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ pada sipo wọn, atawọn ẹsun mi-in.

A gbọ pe Adamu parọwa sawọn aṣofin naa pe ki wọn simẹdọ, ki wọn si fun oun ati igbimọ iṣakoso oun laaye lati yanju gbogbo ohun to n bi wọn ninu, wọn si tun rọ wọn lati ro ti ẹgbẹ oṣelu APC, tori bi wọn ba ṣe bẹẹ ya lọ, eyi le sọ APC di ẹgbẹ oṣelu tọmọ ẹgbẹ rẹ kere ju lọ nile aṣofin naa, ọpọ anfaani leyi yoo si gbegi dina rẹ.

Ni bayii, ẹgbẹ oṣelu APC ni sẹnetọ mejilelọgọta, PDP ni mọkandinlogoji, NNPP ni mẹta, Labour Party ni meji, APGA (All Progressives Grand Alliance) ati YPP (Young Peoples Party) si ni ẹyọ kọọkan.

Ko ti i daju boya awọn aṣofin tinu n bi ọhun ti gba lati jeburẹ, ṣugbọn iparọwa ati ifikun lukun ṣi n tẹsiwaju, gẹgẹ bi ẹnikan to wa nipade naa ṣe sọ.

CAPTION

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: