Lẹyin ti Abdullahi pari ere idaraya tan lo lọọ ko si kanga n’Ilọrin, oku ẹ ni wọn gbe jade

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaide, opin ọṣẹ to lọ yii, ni iṣẹlẹ kayeefi kan ṣẹlẹ lagbegbe Ọlọjẹ Estate, niluu Ilọrin, nibi ti ọkunrin kan, Alaaji Suleiman Abdullahi, ti ọpọ eniyan mọ si “cosia” ẹni ọdun mẹtalelaaadọta, ti bẹ sodo, oku ẹ ni wọn gbe jade ninu omi ọhun.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin to jẹ oṣiṣẹ ileewe gbogbonise Poli tipinlẹ Kwara (Kwara State Polytechnic), lo ji ni owurọ kutu ọjọ Ẹti yii, to si lọọ ṣe ere idaraya gẹgẹ bi wọn lo ṣe maa n ṣe e lojoojumọ.

Lẹyin to n pada bọ nibi to ti lọọ ṣe ere idaraya yii lo ba bọ gbogbo ẹwu ọrun rẹ silẹ, o si lọọ ko sinu sinu kanga to wa niwaju ile rẹ, sugbọn ko si ẹnikankan nitosi lasiko to ko sinu omi naa ti wọn iba sare doola ẹmi rẹ.

Nigba ti awọn eeyan yoo fi mọ ti wọn yoo si fi sa ipa lati yọ ọ jade, ọkunrin naa ti mumi ku, oku rẹ ni wọn gbe jade ninu kanga naa.

Eyi lo mu ki ọpọ awọn to gbọ si iṣẹlẹ naa maa sọ pe ọrọ naa ki i ṣe oju lasan. Wọn ni bawo ni ẹni to lọọ ṣere idaraya, ti ko si ṣẹṣẹ maa ṣe e, yoo ṣe kuro nibi to ti n ṣere naa, ti yoo si waa lọọ ko sinu kanga to wa niwaju ile rẹ, wọn ni ejo ọrọ naa lọwọ ninu.

Ṣa ALAROYE gbọ pe ọn ti sinku ọkunrin naa ni ilana Musulumi.

Leave a Reply