Lẹyin ti Abubakar gbowo itusilẹ lọwọ baba ọmọọdun mẹta to ji gbe lo bo o mọlẹ laaye

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ti sọ pe gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn tan lori ẹsun iwa ọdaran pẹlu ijinigbe ti wọn fi kan afurasi ọdaran kan, Abubarkar Abdulaziz, ẹni ọgbọn ọdun (30), lawọn yoo gbe ẹjọ rẹ lọ si kọọtu fun idajọ to ba yẹ.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni Abubarkar ji ọmọ ọdun mẹta kan gbe lakata awọn obi rẹ lagbegbe Bacirawa, nijọba ibilẹ Musawa, nipinlẹ Katsina, laipẹ yii.

Nigba ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, CSP Isah Gambo, n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o ṣalaye pe ṣe ni Abdulaziz lọọ ji ọmọ ọdun mẹta kan gbe lakata baba rẹ ni Bacirawa, nijọba ibilẹ Musawa, lakooko ti baba ọmọ naa n sun lọwọ. Lẹyin to ji ọmọ ọhun gbe tan lo ba kọ lẹta si baba ọmọ yii pe ko lọọ wa ẹgberun lọna ẹgbẹrin Naira (N800,000) wa to ba mọ pe oun ṣi fẹẹ foju kan ọmọ oun laaye. O tun kọ nọmba foonu rẹ kan ti baba ọmọ naa fi le ba a sọrọ sinu lẹta to fi ranṣe si i.

‘’Lẹyin ọpọlọpọ idaamu pẹlu ẹbẹ lati ọdọ baba ọmọ naa pe ko sibi ti oun ti fẹẹ ri iru owo to beere yii, ọdaju ọmọkunrin yii gba lati gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) lọwọ baba ọmọ ọhun.

‘’Wọn wọna, wọn fi owo yii ranṣẹ si Abubakar. Ṣugbọn pẹlu bo ṣe gba owo ọhun, ko tu ọmọ naa silẹ nigbekun rẹ gẹgẹ bii adehun to ṣe pẹlu baba ọmọ naa. Eyi ti iba fi tu ọmọ naa silẹ, niṣe lo bo o mọlẹ laaye, to si ṣe bẹẹ gbẹmi ọmọkunrin yii.

‘‘Eyi lo mu ki awọn obi ọmọ yii lọọ fi ọrọ naa to ọlọpaa leti, tawọn agbofinro si bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa’’. Awọn ọlọpaa ni gbara tawọn ti gbọ sọrọ naa lawọn ti ṣiṣẹ lori rẹ, tọwọ awọn si tẹ Abubarkar Abdulaziz nibi to sa pamọ si.

O ni lasiko ti wọn n fọrọ po o nifun pọ lo jẹwọ pe loootọ oun loun ji ọmọ naa gbe. Bẹẹ lo ni oun gba owo lọwọ baba rẹ, ṣugbọn gbara toun ti gba owo naa tan loun ti lọọ bo ọmọ ọdun mẹta naa mọlẹ laaye, nigba toun ko mọ boun aa ṣe ṣorọ ọmọ naa si.

 

Leave a Reply