Pẹlu ibanujẹ ni adajọ ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Delta, Anthony Okorodas, fi ṣalaye pe ọmọ mẹta ti iyawo oun akọkọ bi foun ki i ṣe toun, lẹyin ti oun ti tọ meji pari nile-ẹkọ yunifasiti.
Adajọ yii ṣalaye pe ẹnikan lo ṣofofo ọrọ naa foun pe ọkan ninu awọn ọmọ mẹta ti iyawo toun kọkọ fẹ bi foun ki i ṣe ọmọ oun lasiko ti Korona n ṣoro gidigidi ninu oṣu kẹrin, ọdun to kọja.
Ọkunrin naa ni eyi lo mu ki oun gbe igbesẹ akin nipa ṣiṣẹ ayẹwo ẹjẹ fun ọmọ naa lati fidi ọrọ yii mulẹ.
Okorodas ni aṣiri ayẹwo ẹjẹ toun ṣe yii lo fidi rẹ mulẹ pe ọmọ naa ki i ṣe toun loootọ. Ṣugbọn nigba toun gbe ọrọ yii ko iya wọn loju, o kọkọ sẹ kanlẹ pe ko si ohun to jọ bẹẹ, o ni ọmọ oun ni.
Ṣugbọn nigba to ya lo pada jẹwọ pe ki i ṣe ọmọ oun loootọ, o ni ọkunrin mi-in toun n jade pẹlu rẹ nigba ti oun ṣi wa nile oun lo ni ọmọ yii.
Baba yii ni aṣiri ti obinrin yii tu lo mu ki oun lọọ ṣẹ ayẹwo ẹjẹ fun awọn ọmọ meji yooku to bi fun oun lati mọ boya awọn naa ki i ṣe ọmọ oun.
Ni ọjọ diẹ sẹyin ni esi ayẹwo ẹjẹ naa de, to si han pe awọn ọmọ mejeeji yii naa ki i ṣe ọmọ oun. Eyi tumọ si pe gbogbo ọmọ mẹtẹẹta ti iyawo naa bi fun oun ni ki i ṣe toun.
Bakan naa lo ni oun ti lọọ ṣẹ ayẹwo fun awọn ọmọ mẹrẹẹrin ti iyawo ti oun fẹ ṣikeji bi, esi ayẹwo naa fi han pe oun loun ni awọn ọmọ mẹrẹẹrin.
Ọkunrin adajọ yii ni pẹlu aṣiri to tu yii, oun ko ni i dẹyin ninu titọju awọn ọmọ to ni ọkan ti jade nileewe giga fasiti ninu wọn, ekeji yoo si pari laipẹ yii, bẹẹ ni ikẹta wa nileewe girama alaadani kan, to si jẹ pe awọn naa lawọn n sanwo ileewe wọn titi di asiko yii.
O fi kun un pe latibẹrẹ ni iyawo ti oun ṣẹṣẹ fẹ yii ti ri awọn ọmọ naa bii ọmọ to bi ninu ara rẹ, to si n tọju wọn, bẹẹ ni awọn ko ni i dawọ duro ninu ṣiṣẹ eleyii.