Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori iku ọmọbinrin kan, Shakirat, ẹni ti wọn ba oku ẹ lẹyin sọọbu iya rẹ lagbegbe Oke-Oore, niluu Iwo, nipinlẹ Ọṣun.
Shakirat, ẹni ọdun mejilelogun, la gbọ pe o di awati l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, iyẹn ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹta, ọdun yii, ti awọn mọlẹbi rẹ si n wa a kaakiri.
Ṣugbọn ṣe ni wọn ba oku rẹ lẹyin ṣọọbu iya rẹ gan-an laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee ana, ti gbogbo awọn ti wọn ri i figbe ta.
Alaroye gbọ pe wọn fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa ilu Iwo leti, awọn ọlọpaa si gbe oku rẹ lọ sile igbokuu-si ti Iwo General Hospital.
Ẹnikan to n gbe agbegbe naa, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun, sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn afoniṣowo ni wọn gbe ọmọ naa, ati pe lẹyin ti wọn yọ nnkan ti wọn nilo lara rẹ tan ni wọn lọọ ju oku rẹ sẹyin ṣọọbu iya rẹ.
Amọ sa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹ.
Ọpalọla fi kun un pe ohun ti awọn fẹẹ ṣe ni lati ṣayẹwo oku Shakirat lọsibitu, lati le fidi iru iku to pa a gan-an mulẹ, ṣugbọn awọn mọlẹbi rẹ yari pe awọn fẹẹ sinku ẹ, idi niyẹn tileeṣẹ ọlọpaa fi yọnda rẹ fun wọn.