Lẹyin ti awọn onimọto din owo ọkọ ku l’Ekiti, ijọba rọ awọn ọlọja naa lati ṣe bẹẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti ṣeleri idẹra fun awọn araalu lori bi nnkan ṣe gbẹnu soke lẹka eto ọrọ-aje, paapaa lori ounjẹ ati igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa. Eyi waye lẹyin ti ẹgbẹ awọn awakọ din owo ọkọ ku latari arọwa tijọba pa fun wọn.

Iwadii ALAROYE fi han pe owo tawọn awakọ n gba nipinlẹ Ekiti lo pọ ju nilẹ Yoruba, eyi si ti wa ki arun Koronafairọọsi too de, afi bi arun naa ṣe de tawọn awakọ tun gbe owo gọbọi le owo mọto lai ni idi pataki kan.

Alaye tawọn eeyan naa gbe kalẹ nipasẹ Alaga ẹgbẹ awọn awakọ, Road Transport Employers’ Association of Nigeria (RTEAN), Rotimi Ọlanbiwọnninu, ni pe ijọba fi kun owo epo bẹntiroolu, owo gọbọi gun ẹya ara ọkọ, bẹẹ ni wahala Koronafairọọsi da nnkan nla silẹ fawọn onimọto.

Lati bii ọsẹ meji sẹyin nijọba ti n gbe igbesẹ lati jẹ kawọn awakọ naa din owo ọkọ ku, eyi si so eeso rere lopin ọsẹ to kọja nigba tawọn ẹgbẹ naa para pọ, ti wọn si gba lati din owo ọkọ ku.

Nibi ipade kan ti Ọnarebu Biọdun Ọmọlẹyẹ to jẹ Olori oṣiṣẹ fun Gomina Kayọde Fayẹmi ṣagbekalẹ nile ijọba lawọn awakọ ti sọ pe Ado-Ekiti si Akurẹ ti di ẹẹdẹgbẹrun naira (N900) lati ẹgbẹrun kan aabọ (1,500) to wa tẹlẹ, nigba ti Ado-Ekiti si Eko ti di ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹta naira (N2,500) lati ẹgbẹrun mẹta ati ẹẹdẹgbẹta naira (N3,500).

Bakan naa ni Ado-Ekiti si Ibadan ti dinku si ẹgbẹrun kan bọ (N1,500) lati ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹta naira (N2,500), bẹẹ ni owo ọkọ si Onitsha ti di ẹgbẹrun mẹta ati ẹẹdẹgbẹta naira (N3,500) lati ẹgbẹrun marun-un ati igba naira (N5,200).

Ijọba waa ṣeleri lati ran awọn awakọ naa lọwọ pẹlu ọkọ bọọsi igbalode, awọn ẹya ara ọkọ atawọn eto ironilagbara loriṣiiriṣii laipẹ.

Ni bayii, bi owo awọn nnkan ounjẹ yoo ṣe walẹ lawọn araalu n duro de bayii pẹlu bi ijọba ṣe sọ pe awọn babalaje ati iyalọja tọrọ kan, dandan si ni kawọn naa dẹkun owo gọbọi ti wọn n gbe le ọja wọn, paapaa niluu Ado-Ekiti.

Leave a Reply