Adewale Adeoye
Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Festac, ni gende kan, Emmanuel Chukwuma, ẹni tawọn eeyan mọ si Oliver, ẹni ọdun marundinlaaadọta wa bayii, o n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan an pe o fọbẹ aṣooro kan gun ọrẹbinrin rẹ, Oloogbe Abọsẹde Adefẹyinti, pa lasiko tija nla ṣẹlẹ laarin wọn.
ALAROYE gbọ pe edeaiyede kekere kan lo waye laarin awọn ololufẹ meji naa ti wọn n gbe ni ‘7th Avenue, ni Festac, nipinlẹ Eko, lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ki awọn araale si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Oliver ti gun ololufẹ rẹ pa.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa ti iṣelẹ ọhun ṣoju rẹ to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ololufẹ ni Oliver ati oloogbe naa, ọdọ Oliver ni Abọsẹde n gbe lagbegbe 7th Avenue. O ni Oliver ko niṣẹ gidi kankan lọwọ, iyawo rẹ yii lo n bọ ọ.
Iṣẹ agbo ati agunmu tita ni oloogbe naa n ṣe. Nigba mi-in ti awọn onibaara ba pọ lọdọ rẹ, Oliver maa n ran an lọwọ lati ba a taja fun wọn.
Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, nija kekere kan waye laarin awọn mejeeji, eyi to mu ki Oliver gun ololufẹ rẹ pa patapata. Lẹyin to pa a tan, lo gbiyanju lati bẹ sinu kanga kan to wa lẹgbẹẹ ile rẹ, ṣugbọn awọn araale di i mu, wọn ko jẹ ko ṣe bẹẹ titi ti wọn fi fa a le awọn ọlọpaa agbegbe naa lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, sọ pe ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ Aje, ni iṣẹlẹ naa waye.
O ni awọn maa too ṣewadii nipa ohun to dija silẹ laarin awọn mejeeji.