Faith Adebọla, Eko
Afaimọ ki ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun yii, Fatai Ismaila, ma pada sibi to ti n bọ bayii, latari bawọn ọlọpaa ṣe tun fi pampẹ ofin gbe e fun ẹsun idigunjale, bẹẹ ko ti i ju ọdun meji aabọ lọ to jade lẹwọn lori ẹsun ole jija.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, lo sọrọ yii f’ALAROYE ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ. O ni opin ọsẹ to kọja, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ni afurasi ọdaran yii lọọ fọ ileetaja igbalode kan to wa ni ibudokọ Fọlarin, laduugbo Langbasa, l’Ajah, nipinlẹ Eko, lo ba sa lọ.
O ni Fatai, ti orukọ inagijẹ rẹ n jẹ ‘Small’ ko ribi fori mu si tori ọjọ meji lẹyin naa lawọn agbofinro lati teṣan Ajah pada ri i mu, awọn aladuugbo atawọn fijilante agbegbe naa ni wọn dọdẹ ẹ tọwọ fi ba a.
Ibọn oyinbo kan ni wọn ka mọ ọn lọwọ, o lọwọ ọkunrin kan tiyẹn ti sa lọ bayii loun ti ra a, wọn si tun ba awọn ọta ibọn ti ko ti i yin rẹpẹtẹ, egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni, ada ati ọbẹ ni sakaani afurasi yii.
Igba ti wọn wọ ọ de teṣan wọn laṣiiri tu pe Fatai ‘Small’ kan naa ti wọn ran lẹwọn lọdun 2017 fun ẹsun idigunjale lọwọ wọn tun tẹ pada yii. Wọn ti fi ọrọ naa to kọmiṣanna ọlọpaa Eko leti, o si ti paṣẹ pe ki wọn taari ẹjọ rẹ sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii gidi.
Adejọbi ni tiwadii ba ti pari, Fatai maa balẹ sile-ẹjọ ni.