Lẹyin ti Favour ati Precious ta ile-ọmọ wọn lowo ti ko to nnkan lọsibitu laisan nla kọ lu wọn

Monisọla Saka

Ko ṣeni to ti i le sọ boya aimọkan ni o, boya ifẹ owo, lo mu ki awọn ọmọdebinrin meji kan, Precious ati Favour ti wọn n gbe n’Iyan-Ipaja, niluu Eko, ta ẹya ara wọn ni owo ti ko to nnkan. Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira ni wọn ta ile ọmọ wọn atawọn ẹya ara mi-in fun dokita kan niluu Abẹokuta, lai fi to awọn obi wọn leti, bẹẹ lawọn dokita yii naa ko bikita lati wa awọn obi wọn kan ki wọn si gbaṣẹ lọwọ wọn. Ọrọ naa ti yiwọ bayii, iwadii si ti fi han pe ẹdọ, ile-ọmọ, ile-itọ, kindinrin, oronro atawọn ẹya ara mi-in awọn ọmọdebinrin yii ti bajẹ.

Iṣẹ akọwe ni Precious n ṣe ni ṣọọṣi kan, wọn si n fun un lẹgbẹrun lọna ogun Naira (20,000) loṣu, nigba ti Favour jẹ aṣerun-lọṣọọ. Obinrin agbalagba kan ti wọn jọ n lọ sile ijọsin kan naa, Abilekọ Adeleke, ni wọn lo sọ pe owo ti wọn n san fun awọn ọmọ naa nibi iṣẹ wọn kere, oun yoo mu wọn lọ sibi ti wọn ti le ri owo to pọ gba.

Adeleke yii lo mu wọn lọ sileewosan kan ti wọn n pe ni Redwood Specialist Hospital, Abẹokuta. Nibẹ ni wọn ti fun ọkọọkan awọn ọmọbirin mejeeji ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (100, 000), lẹyin ti wọn yọ ohun ti wọn fẹ ninu ara wọn tan.

Lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni aṣiri ọrọ naa tu gẹgẹ bi akọroyin iweeroyin Vanguard to ṣiṣẹ iwadii naa ṣe sọ. Ọkan ninu awọn ọmọbinrin yii lo bẹrẹ si i bi, eyi lo jẹ ki baba rẹ ro pe aisan iba jẹfun-jẹdọ, taifọọdu (typhoid), lo n ṣe e, lo ba gbe e lọ si ọsibitu fun itọju.

Nibẹ ni dokita ti ṣalaye fun wọn pe awọn yoo ṣe awọn ayẹwo kan fọmọbinrin ọhun ki awọn too bẹrẹ itọju. Asiko ayẹwo naa ni wọn ri i pe oju ara ati oju ibi to ti n yagbẹ ti bajẹ.

A gbọ pe niṣe ni ọmọbinrin yii daku rangbọndan, nigba to pada laju saye pẹlu itọju ti wọn fun un lo jẹwọ fun baba rẹ pe obinrin kan ni ṣọọṣi awọn lo ko awọn lọ sọdọ dokita kan ti wọn ti yọ ẹya ara awọn l’Abẹokuta.

O tẹsiwaju pe obinrin yii lo sọ fawọn pe owo taṣẹrẹ ni Biṣọọbu to gba ọkan ninu wọn siṣẹ n fun un. O waa ṣeleri lati mu awọn lọ si ibi ti wọn yoo ti sanwo to pọ, bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira fawọn. Bẹẹ lo ki wọn nilọ lati ma ṣe sọ fawọn obi wọn tabi ẹnikẹni, o ni bi awọn ba ṣe bẹẹ, iku ni.

Ọmọbinrin yii ni Redwood Hospital, l’Abẹokuta, lo ko awọn lọ  lọdọ Dokita Durodọla, to kọkọ gun awọn labẹrẹ. Lẹyin naa lo ni wọn fi tipatipa wọ awọn lọ si PDF Hospital, to wa ni Surulere, l’Ekoo, nibi ti wọn ti fi agbara mu awọn, ti wọn si yọ ẹyin to n dọmọ ninu obinrin ẹgg ninu ile ọmọ wọn (Ovaries), lọna aitọ lara awọn, lai jẹ pe wọn bi awọn boya o tẹ awọn lọrun. Wọn ni gbogbo nnkan ti wọn ṣe fawọn yii lo yọri si inira tawọn n kọju ati ẹjẹ to n ya lara awọn.

Alaye tawọn ọmọ wọnyi ṣe lo mu ki awọn obi wọn gbe wọn lọ si ọsibitu mi-in lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, nibẹ ni wọn ti ṣe ayẹwo mi-in fun wọn, ti abajade rẹ si fi han pe ẹdọ, ile-ọmọ, ile-itọ, kindinrin, oronro atawọn ẹya ara mi-in ninu wọn ti bajẹ latari iṣẹ abẹ ti wọn ṣe fun wọn.

Ṣugbọn Arabinrin Adeleke ṣalaye pe “Awọn ọmọ yẹn ni wọn finu-findọ jọwọ ara wọn nile iwosan naa. Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ni wọn fun wọn lati fi ẹmi imoore han, Favour ni tiẹ fun mi ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira (20,000), lati dupẹ pe lati ọdọ mi ni wọn ti mọ nipa iṣẹ yẹn, ti mo si tun ṣe atọna wọn de ọsibitu ọhun”.

Biṣọọbu lo funra ẹ gba teṣan ọlọpaa Iyana-Ipaja lọ lati lọ fọrọ naa to wọn leti, tawọn yẹn si taari ẹjọ ọhun lọ si ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran(SCID), Panti, Yaba, nipinlẹ Eko fun iwadii to lọọrin.

A gbọ pe ajọ to n gbogun ti gbigbe eeyan lọna aitọ lọọ ṣiṣẹ ipa tabi aṣẹwo loke okun (NAPTIP), ti bẹrẹ iwadii lakọtun lori ọrọ yii.

Agbẹnusọ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundenyin, ṣalaye pe, “Ọna to ba ofin mu lawọn dokita akọṣẹmọṣẹ ọhun fi ṣe e, wọn ki i si i ṣe awọn ti wọn n fipa wa ẹya ara eeyan. Gbogbo awọn iwe to yẹ lawọn ọmọ yẹn tọwọ bọ, wọn si tun kọ ọ sibẹ pe awọn ti le lọmọ ọdun mejidinlogun. Bakan naa ni dokita sọ fun wọn pe ọjọ meji lẹyin ti wọn ba ṣe e tan, inu ara yoo maa dun wọn, wọn si gba bẹẹ lati fi ẹya ara wọn silẹ.

‘‘Ohun to ba ni lọkan jẹ ni pe wọn ko fọrọ naa to baba wọn leti ki wọn too ṣe e, baba wọn si ti ta ku pe miliọnu lọna igba Naira (200 million) loun maa gba gẹgẹ bii owo gba-ma-binu”.

Leave a Reply