Lẹyin ti Jẹlili gba idajọ iku l’Abẹokuta, adajọ tun ni ki oku rẹ ṣẹwọn ọdun mẹwaa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

A oo yẹgi mọ ọ lọrun titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ, ki Ọlọrun ṣaanu fun ẹmi rẹ’

Adajọ Abiọdun Akinyẹmi ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun to wa niluu Abẹokuta lo sọ ọrọ yii nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ọkunrin kan, Jẹlili Agẹmọ, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36) ti wọn fẹsun idigunjale ati nini nnkan ija ogun lọwọ kan, ti wọn si lo jẹbi awọn ẹsun ọhun.

Adajọ sọ pe kedere lo foju han pe adigunjale ni Jẹlili, bẹẹ lo ni awọn ibọn ti ofin ko faaye gba lati maa gbe kiri lọwọ. Ole lo si n fi awọn ibọn naa ja pẹlu awọn irinṣẹ mi-in ti wọn tun ka mọ ọn lọwọ.

Yatọ si pe wọn yoo yẹgi fun Jẹlili Agẹmọ, Adajọ Akinyẹmi tun paṣẹ pe oku rẹ yoo ṣẹwọn ọdun mẹwaa, eyi to wa fun awọn nnkan ija ti ko yẹ ko ni lọwọ ti ijọba ba lọwọ rẹ.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ ti ẹni kan ṣoṣo yoo fi koju ijiya nla bii eyi, Agbefọba, Ọlajumọkẹ Ogunbọde, ṣalaye pe lọjọ kẹwaa ati ikẹrinla, oṣu kẹwaa, ọdun 2009, iyẹn ọdun mọkanla sẹyin, ni  Jẹlili digunjale l’Opopona Majẹkẹmbo, loju ọna to gba Quarry kọja, l’Abẹokuta.

O ni Jẹlili pẹlu awọn mẹfa mi-in ni wọn jọ gbimọ jale, ti wọn n wọle awọn olugbe adugbo naa, ti wọn n ko wọn ni dukia, ti wọn si ko wọn laya soke roro pẹlu awọn nnkan ọsẹ ti wọn ko dani gbogbo.

Eeyan mẹfa ni Agbefọba Ogunbọde sọ pe wọn ja lole lawọn asiko ti wọn pitu naa, awọn naa ni: Abilekọ Adeile Kẹmi,  Abilekọ Adegbe Grace, Ọmọọwe O.O Dipẹolu, Abilekọ Ọlakunle Olubukọla,  Ṣeun Adelana  ati Ọshọ Mercy.

Awọn nnkan bii foonu, kọmputa, ẹṣọ ara bii goolu ati owo lo ni olujẹjọ atawọn yooku ẹ ko lọ nile awọn ti wọn pitu fun naa.

Ibọn mẹta ati ọta ibọn mejidinlogun lo ni awọn ọlọpaa ba lara Jelili nigba tọwọ tẹ ẹ, bẹẹ ni ko ni iwe-aṣẹ lati maa gbe awọn ibọn naa kiri.

Ofin to de nini nnkan ọṣẹ bii eyi lọwọ lorilẹ-ede yii, eyi ti wọn ṣe lọdun 2004, lo de Jẹlili, ohun lo si fa a ti Adajọ fi dajọ rẹ ni lile koko.

 

Leave a Reply