Lẹyin ti mo ba lo ọdun mẹjọ pe, oloṣelu to ba gbọn ṣaṣa ni ma a gbejọba fun – Tinubu

Gbenga Amos

 Eekan oloṣelu, to tun jẹ gomina ipinlẹ Eko nigba kan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe oko bi itẹsiwaju yoo ṣe maa gori itẹsiwaju loun n ṣan lọwọ yii pẹlu boun ṣe fa ara oun kalẹ lati jade dupo aarẹ lọdun 2023, o ni toun ba wọle, toun si pari saa meji lọdun mẹjọ, oun maa ri i daju pe oloṣelu ti yoo gba akoso lẹyin oun gbọdọ jẹ ẹni to gbọn fefe, to si lero lẹyin ju lọ.

Ipinlẹ Ondo, laafin Deji tilu Akurẹ, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi, ni Tinubu ti sọrọ yii lasiko irin-ajo ati abẹwo to n ṣe kaakiri ọdọ awọn ọba alaye nilẹ Yoruba, lati ba wọn fikunlukun lori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Tinubu ni bawọn araalu ba fi le fibo wọn gbe oun wọle sipo aarẹ, oun maa sa gbogbo agbara oun lati tun Naijiria ṣe ni, o ni ọpọ anfaani ati ilọsiwaju to yẹ ki orileede yii ni loun maa hu jade, tori oun gbagbọ pe ibi to yẹ ki Naijiria wa kọ lo wa yii.

“Ti mo ba ṣejọba fun ọdun mẹjọ, ma a gbejọba fun oloṣelu ti muṣemuṣe rẹ da muṣemuṣe, to gbọn fefe, to si lero lẹyin ju lọ, oun lo maa gba akoso lọwọ mi ti mo ba ti pari saa temi.

‘‘O ṣe ni laaanu pe Naijiria ko le ṣe paadi bireeki ọkọ lasan, ọpọ nnkan keekeekee la ṣi n ko wọlu latilu oyinbo, idagbasoke ti a ni ko tẹwọn rara. Ma a yi Naijiria po si rere ti mo ba dori aleefa.

‘‘Gbogbo nnkan ti mo fẹ ni adura ati atilẹyin yin ki n le depo aarẹ. Ọmọ yin lo fẹẹ dije, emi si lọmọ yin ọhun.

Ipinlẹ Eko lo bajẹ ju lọ nilẹ Afrika nigba ti mo di gomina, owo perete la n pa wọle nigba yẹn, ṣugbọn a ṣa gbogbo ipa wa, ẹ wo Eko lonii, owo to n pa wọle ju ogoji biliọnu lọ.”

Tinubu, to jẹ adari apapọ fẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) tun ṣeleri pe ipese iṣẹ yanturu, ati dida awọn ileeṣẹ nla nla silẹ wa lara ohun to maa jẹ oun logun gidi, gẹgẹ bii aarẹ Naijiria.

Leave a Reply