Lẹyin ti Ojo atawọn ọrẹ ẹ fipa ba ọmọ lo pọ tan ni wọn tun fẹẹ ki iya mọlẹ n’Ikarẹ-Akoko

 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ. 

 

Awọn afurasi mẹrin ti wọn fẹsun ifipabanilopọ kan ni wọn ti n jẹjọ lọwọ nile-ẹjọ Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ.

Awọn olujẹjọ ọhun, Ojo Damilọla, Babalọla Bọdunde, Jimoh Fatai ati Saliu Abdul ni wọn fẹsun kan pe wọn fipa ba ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan lo pọ niluu Ikarẹ-Akoko, lọjọ kẹtadinlọgbọn ati ikejidinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun ta a wa yii.

Bakan naa ni wọn lawọn mẹrẹẹrin tun gbiyanju ati fipa ba iya ọmọdebinrin yii lo pọ ki Ọlọrun too ko o yọ lọwọ wọn.

Iwa ti wọn hu yii ni wọn lo ta ko abala ofin okoolugba o din meji (218) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006. Gbogbo awọn olujẹjọ naa ni wọn lawọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Agbefọba, Taiwo Oniyẹrẹ, ni iyalẹnu nla lo jẹ laaarọ ọjọ igbẹjọ naa pẹlu bi iya ọmọ ti wọn fipa ba lo pọ ṣe yi ohun pada, to si n bẹbẹ fun awọn afurasi ọdaran ọhun.

Agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Ọgbẹni J. O. Adewale bẹ adajọ lati yọnda awọn onibaara oun niwọn igba ti iya ọmọ to lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa ti loun ko ṣẹjọ mọ.

Adajọ J. O. A. Adepọju ni kawọn afurasi ọhun ṣi lọọ maa ṣere lọgba ẹwọn Olokuta titi di ọjọ karun-un, oṣu to n bọ yii. O tun pasẹ fawọn ọlọpaa lati fi ojulowo ati ẹda iwe ẹsun naa ṣọwọ si ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Leave a Reply