Lẹyin ti ọkọ ti tọju ọmọ fun ọdun mẹfa niyawo ṣẹṣẹ sọ pe ale lo ni in l’Ago-Arẹ

Olu-Theo Omolohun Oke-Ogun

Ninu oṣu kejila, ọdun 2009, ni Ọgbẹni Adewale Babatunde ṣegbeyawo alarinrin pẹlu Omidan Ashiata Ọmọlọla niluu Agọ-Arẹ, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si bura pe awọn yoo ṣe oloootọ si ara awọn.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bi wọn ṣe ro mọ bayii latari ẹsun iwa aiṣootọ ti wọn fi kan Ashiata, ọmọ ọdun mẹrinlelogun, latari bi wọn ṣe fura pe oyun ọmọ kẹta to wa nikun ẹ, wọn lọkọ ẹ kọ lo loyun ọhun fun, wọn ni ale lo ni in.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja yii, lakara tu sepo lori ẹsun ọhun, nigba ti baba agbalagba to porukọ ara ẹ ni Tirimisiyu Ọlaoye, to jẹ ale obinrin naa, de lati ilu Ọyọ pe oun fẹẹ gba ọmọ oun.

Ninu alaye ti Ọgbẹni Adewale Arẹmu, ẹni ọdun mejidinlọgọta ti i ṣe baba ọkọ iyawo ṣe f’ALAROYE pẹlu awọn oṣiṣẹ ọfiisi awọn to n tọju ọmọ orukan (Welfare), to wa laduugbo Balako, niluu Ṣaki, o ni ileewe girama ni ọmọ oun ati iyawo rẹ yii ti pade ara wọn, ti wọn si funra aọn loyun.

O tẹsiwaju pe ọmọ mẹta, Easter, ọmọ ọdun mẹtala, Isiah Adewale, ọmọ ọdun mẹsan-an ati Peter Adewale, ọmọ ọdun mẹfa lo wa laarin wọn.

Gẹgẹ bo ṣe wi, lẹyin ti wọn bi ọmọ keji ni ọkọ iyawo, Ọgbẹni Adewale, tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nileewe gbogbo-niṣe Poli Ibadan, to si fi iyawo rẹ sẹnu ẹkọṣẹ awọn aṣerunlọṣọọ.

Ọgbẹni Arẹmu ni ko pẹ, ko jinna, tawọn ọrẹ Ashiat ni ko maa bọ niluu Ọyọ lati maa waa ṣiṣẹ paki (Cassava). O ni laarin oṣu mẹfa to fi wa niluu Ọyọ lawọn gbọ pe o ri ọkunrin kan, wọn si jọ n ṣe wọle-wọde, ẹni ọhun ni wọn lo fun un loyun ọmọ kẹta lai jẹ ki ọkọ rẹ, Adewale, mọ si i, wọn lo tun bẹrẹ si i laṣepọ pẹlu ọkọ rẹ.

Kẹrẹkẹrẹ, ọjọ ikunlẹ pe, lakooko to bi ọmọ naa siluu Ibadan, lọdọ Adewale, ọkọ rẹ, Ọgbẹni Arẹmu, ni ọpọlọpọ owo loun na, yatọ si ti ounjẹ toun n fi ranṣẹ si wọn loorekoore, pẹlu arugbo ara oun.

O ni ijọloju lo jẹ foun pe boun ṣe ṣe wahala lori Ashiata to, abuku ati ẹgbin loun ri latọdọ awọn obi rẹ, oun ko le gbagbọ pe ọmọ naa le maa f’ọbẹ ẹyin jẹ ọmọ oun niṣu, latari bi Tirimisiyu ṣe waa yọju pe oun loun lọmọ tawọn ti n tọ lati bii ọdun mẹfa sẹyin.

Nigba ti wọn bi Ashiata Ọmọlọla leere bọrọ ṣe jẹ, ko mọ ohun to maa sọ mọ, wọn ni niṣe lo n tẹwọ pe ki wọn fori ji oun, o ni loootọ ni ki i ṣe ọkọ oun lo loyun ọmọ kẹta.

O ni idi niyi toun fi n fẹ idajọ ododo lori ọrọ naa, oun si ti ṣetan lati yọnda Peter fun baba rẹ ti wọn ba ti le san miliọnu mẹwaa naira foun fun itọju latinu oyun ati inawo toun ṣe lati ọdun mẹfa sẹyin, tori ọmọ oun (Adewale) ti loun o fẹẹ ri ọmọ ale naa ati iyawo alagbere naa mọ.

Ọjọ Mọnde ọsẹ to n bọ ni ileeṣẹ Welfare sun ipade awọn mọlẹbi mejeeji pẹlu baba ọmọ naa si, wọn si ti fiṣẹlẹ yii to awọn agbofinro leti.

Leave a Reply