Lẹyin ti Tosin digun ja tọkọ-taya lole tan lo tun fẹẹ fipa ba iyawo lo pọ n’Idanre

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ogbologboo adigunjale kan, Tosin Ọmọniyi lọwọ awọn ọlọpaa tẹ niluu Idanre loru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, nibi to ti n gbiyanju ati fipa ba abilekọ kan ta a forukọ bo laṣiiri sun lẹyin to ti kọkọ ja tọkọ-taya ọhun lole owo nla.
Tosin ni wọn lo ka tọkọ-taya ọhun mọle ni nnkan bii aago kan oru ọjọ naa, bo ṣe ja ilẹkun wọ yara yara ti wọn sun si lo na ibọn agbelẹrọ kan to mu lọwọ si wọn, to si paṣẹ fun wọn ki wọn ko gbogbo owo ọwọ wọn jade ti wọn ko ba fẹẹ fiku ṣe ifa jẹ.
Kiakia ni tọkọ-tiyawo ọhun ti sare ko owo to wa lọwọ wọn, eyi to to bii ẹgbẹrun lọna ọtalelugba din mẹwaa Naira (#250, 000) le e lọwọ.
Bo ṣe gbowo ọhun tan lo tun ni ki iyawo oniyawo maa niṣo ni yara rẹ pẹlu erongba ati fipa ba a lo pọ, bi wọn ṣe n wọ inu yara lọhun-un to paṣẹ fun un pe ko bọ sori bẹẹdi loun naa fi ibọn ọwọ rẹ lelẹ lẹgbẹẹ kan ko le raaye bọ sokoto idi rẹ ko too maa kona ibasun fun ẹni ẹlẹni.
Sokoto yii lo ṣi n bọ lọwọ ti ọkọ iyawo atawọn araadugbo kan fi ja wọle, gbogbo wọn suru bo o, wọn kọkọ gba ibọn to mu lọwọ ki wọn too bẹrẹ sii lu oun funra rẹ lalubami.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni lẹyin-ọ-rẹyin lọwọ awọn agbofinro tun tẹ Iya Tosin ati lanlọọdu rẹ ti wọn n ṣe agbodegba fun un.
Ninu alaye ti afurasi ẹni ọdun mejilelogun ọhun ṣe fawọn oniroyin lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo, o ni loootọ loun lọọ ka tọkọ-taya naa mọle pẹlu ibọn lati ja wọn lole nitori ọkada kan ti oun fẹẹ ra, ṣugbọn ti ko sowo rẹ lọwọ oun.
O ni bi oun ṣe wọle lọkọ iyawo ti ko ẹgbẹrun lọna aadọta Naira foun, ṣugbọn ti oun tun fi dandan le e fun iyawo rẹ lati wọ yara lọ ko le lọọ wa owo si i.

Tosin ni bi awọn ṣe de inu yara ti oun si fẹẹ maa ba a sun lobinrin naa bẹrẹ si i kigbe, lojiji lo ni ọkọ rẹ atawọn mẹrin mi-in ja wọle, ti wọn si mu oun lẹyin ti wọn ti kọkọ gba ibọn toun fi n ṣọṣẹ lọwọ oun.
Lori ọrọ iya ati lanlọọdu rẹ ti wọn mu pẹlu rẹ, o ni sababi lasan lọrọ awọn mejeeji jẹ nitori pe ko seyii to mọ ohunkohun rara nipa iṣẹ adigunjale ti oun n ṣe ninu awọn mejeeji.
O ni asiko kan wa ti oun ja ẹnikan lole owo to to bii ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin din mẹwaa Naira (#750, 000) ti oun si sọ fun mama oun lati sin oun lọ sibi ti oun ti fẹẹ fi ra ọkada tuntun, ati pe oun ko sọ aṣiri ibi ti oun ti rowo fun mama oun rara ko too gba lati tẹle oun lọ.
Ni lanlọọdu rẹ ti wọn tun fẹsun kan, Tosin ni kiki ti iyawo Baba onile oun ki oun ni ọsibitu ti wọn kọkọ gbe oun lọ fun itọju latari lilu ti wọn lu oun lo jẹ ki wọn lọọ mu ọkọ rẹ pe o ṣee ṣe koun naa wa lara awọn agbodegba to n ran oun lọwọ lati digunjale.
Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami ti ni awawi lasan ni awọn ọrọ tawọn afurasi mẹtẹẹta tọwọ awọn tẹ n sọ, o ni gbogbo wọn lawọn yoo foju wọn bale-ẹjọ lati lọọ sọ tẹnu wọn laipẹ.
Lara awọn ẹru ofin tawọn ọlọpaa ka mọ ogbontarigi adigunjale naa lọwọ ni, ibọn ilewọ kan, ọkada meji ati tẹlifiṣan igbalode kan.

Leave a Reply