Lẹyin ti Victor atawọn ọrẹ ẹ fipa ba ọrẹbinrin ẹ lo pọ tan ni wọn ju fọto ẹ sori ẹrọ ayeujara l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Eka to n gbogun ti fifi ipa ba ọmọ kekere lajọṣepọ (Juvenile Welfare Centre), ti ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ ọdọ langba mẹrin pẹlu ẹsun pe wọn fipa ba ọmọdebinrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan lo pọ ni Ado-Ekiti.

Gẹgẹ bii Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe awọn mẹrin naa ni: Miracle Emmanuel, ẹni ọdun mọkandinlogun (19), Bello Tunde, ẹni ogun ọdun (20), Peace Osho, ẹni ogun ọdun (20), ati Emmanuel Oluwaseun, ẹni ọdun mejilelogun (22).
Nigba to n sọ iriri rẹ fun awọn ọlọpaa, ọmọdebinrin naa sọ pe lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ gan-an, ọrẹkunrin oun ti orukọ rẹ n jẹ Victor, ti awọn ọlọpaa ṣi n wa lọwọlọwọ lo pe oun pe ki oun waa ba oun nileetura kan ni Ado-Ekiti, ṣugbọn oun sọ fun un pe oun ko le wa si agbegbe ti ile itura naa.
O ni lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ, oun gba lati waa ba a nileetura naa.
Ọmọdebinrin ti ko fẹ ki ALAROYE darukọ oun naa sọ pe ni kete ti oun de ibẹ ni oun ba ololufẹ oun ati awọn ọrẹ rẹ mẹrin miiran nibi ti wọn ti n ṣere, ti wọn n mu ọti lile, ti wọn si tun n mu igbo ati egboogi miran to le pupọ.
O ni ọrẹkunrin oun yii fun oun ni ọti kekere kan to wa ninu igo. O ni ni kete ti oun mu ọti yii tan ni oun ko mọ ibi ti oun wa mọ, lẹyin wakati diẹ loun ri i pe ọkan lara awọn ọrẹ ololufẹ oun yii wa lori oun nibi to ti n ba oun lo pọ, ti awọn yooku si n ya fidio oun.
Ọmọbinrin yii fi kun un pe ni kete ti iye oun sọ loun bẹ wọn pe ki wọn pa fidio naa rẹ kuro lori ẹrọ ilewọ wọn, ṣugbọn ti wọn kọ lati pa a rẹ.
Lẹhin ọjọ karun-un loun ri fidio naa lori ẹrọ ayelujara, eyi to ni o fa a ti oun fi lọọ fi ọrọ naa to ọlọpaa leti, ti wọn si fi panpẹ ofin mu awọn ọdaran mẹrin naa.
Alukoro sọ pe akitiyan ti n lọ lọwọ lati mu awọn ọdaran yooku ti wọn ti sa lọ.

Abutu ni ọkan lara awọn ọdaran naa ti jẹwọ pe loootọ ni oun ba ọmọdebinrin naa lajọṣepọ loju awọn yooku, ti wọn si n ya oun ni fidio bi oun ṣe n ṣe ‘kinni’ fun un.
O ṣeleri pe gbogbo eto lo ti to lati ko awọn ọdaran naa lọ sile-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ naa.

Leave a Reply